FUOYE protest: Gómìnà Fayemi ní àsìkò tó fún ọlọ́pàá láti máa lo ọta rọ́ba fún kíkojú ìwọ́de

Gomina KAyode Fayemi Image copyright Ekiti state government

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi ni oun ti paṣẹ fun kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti lati bẹrẹ iwadii ni kiakia lori wahala to bẹ silẹ nilu Ọyẹ Ekiti ni ọsẹ to kọja.

Wahala naa waye laarin awọn akẹkọọ, awọn olugbe ilu naa atawọn ọlọpaa ni ọjọ Iṣẹgun to kọja.

Ninu ọrọ to ba awọn eeyan ipinlẹ Ekiti sọ lalẹ ọjọ Aiku, gomina Fayẹmi ni iwadii ọlọpaa ni yoo ṣafihan gbogbo awọn ti aje iṣẹlẹ naa ba ṣi mọ lori yala laarin awọn ọlọpaa ni tabi laarin ilu.

"Mo ti rọ awọn ọlọpaa lati wa ọna lilo ọta onirọba lati koju iwọde dipo lilo ọta ibọn tootọ."

O ni oun yoo tun gbe arọwa naa de agbo ẹgbẹ awọn gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria, NGF ki wọn lee yẹẹ wo titi de ipele ijọba to ga ju lorilẹede yii.

O ni inu oun dun pe awọn alaṣẹ fasiti naa atawọn igbimọ adari akẹkọọ nibẹ pẹlu ti kọkọ sọọ ṣaaju pe kii ṣe iyawo oun tabi awọn oṣiṣẹ ijọba to baa kọwọrin lo paṣẹ fun awọn ọlọpaa lati yinbọn lasiko iṣẹlẹ naa. O ni o han gbangba pe iyawo oun kan rin arinfẹsẹsi ni.

Image copyright Ekiti state government

Lori ọrọ aisi ina ọba to ṣokunfa iwọde awọn akẹkọọ ni owurọ ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, Gomina Fayẹmi ni ọpọ igba ni oun ti ran ikọ lọ sọdọ awọn alaṣẹ amunawa BEDC bi o tilẹ jẹ pe gomina ipinlẹ ko laṣẹ tabi agbara kankan lori ipese ina manamana lorilẹede Naijiria.

O fi kun un pe ijọba ni yoo san owo itọju awọn to fara gbsgbẹ lasiko iṣẹlẹ naa ati wi pe ko dun mọ ijọba ipinlẹ naa ati oun ninu pe iku pa awọn ọjọ ọla orilẹede yii meji kan lasiko ti rogbodoiyan naa fi waye.