Wo àwọn ọ̀nà to fi leè ní owó lọ́wọ́ láti ipasẹ̀ iṣẹ́ amọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Pottery: Àwọn onímọ̀ nípa amọ̀ wúlò púpọ̀ ju ike àbí irin lọ

Lara awọn isẹ isẹnbaye wa nilẹ Yoruba ni amọ mimọ jẹ eyi to n mu owo wa fun ọpọ eeyan.

Ṣugbọn lode oni, isẹ yii ti n parun lọ diẹdiẹ, idi si ree ti BBC Yoruba fi tọ awọn to n mọ amọ lati mọ ọna ti wọn n gba ki isẹ amọ ma baa parun.

Nigba ti wọn n ba BBC sọrọ, onisẹ ọna kan to n lo amọ lati fi mọ ere, Iyiọla Soẹtan kede pe lootọ ni isẹ amọ ti n parun lọ nitori ọpọ eeyan ko setan lati kọ isẹ naa tori pe o jẹ isẹ idọti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa ke si awọn eekan ninu isẹ ọna to n lo amọ lati se koriya fun awọn ọdọ ki a lee se agbende isẹ amọ pada bii ti aye atijọ.

Bakan naa ni iya onikoko kan to n lo amọ lati fi mọ ikoko sọ fun wa pe ko si bo ti wu ko ri, isẹ amọ ko lee parun nitori iwulo ikoko ti wọn n fi amọ mọ si ọpọ eeyan.

O wa fi ọwọ gbaya pe owo wa ni idi rẹ, ti oun si n ri taje se nibẹ nitori isẹ amọ pe ju lilo ike abi irin lati fi rọ ohunkohun lọ.

'Ojú mi rí tóó, àwọn ìyàwó kìí ṣiṣẹ́, ọkọ àtàwa ọmọ-ọ̀dọ̀ laláṣekú lórílẹ̀èdè Oman'