Mile 12 Accident: LASEMA ní ọkọ̀ akẹ́rù tó sọ ìjánu rẹ̀ nù lásìkò eré àsápajúdé ló fa sábàbí

Kọntena kan wo lu ọkọ ayọkẹlẹ Image copyright LASEMA

Ijamba o nile afi ki ọba oke maa ko wa yọ, Ijamba miran tun ti sẹlẹ ni agbegbe Agric, lopopona Mile 12 si Ikorodu nilu Eko.

O kere tan eeyan meji ti dagbere faye ninu ijamba naa, awọn mẹta wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nigba ti ọpọ eeyan miran farapa.

Ohun to fa sababi isẹlẹ naa ni bi ọkọ akẹru nla kan to gbe ile ẹru onirin, taa mọ si kọntena, to gun to ogun bata se wo lu ọkọ ayẹkẹlẹ Camry kan, ti nọmba rẹ jẹ FKJ 732 FS to si pa awọn eeyan to wa ninu rẹ.

Image copyright LASEMA

Koda, a gbọ pe awọn ọlọkada atawọn eeyan to to n rin lọ lasiko ti ijanba naa waye naa wa lara awọn to fara pa.

Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, Ọga agba fun ajọ to n mojuto isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, Ọmọwe Olufẹmi Oke Ọsanyintolu salaye pe gbogbo awọn osisẹ awọn lo tete lọ sibi ti isẹlẹ naa ti waye.

Image copyright LASEMA

Ọsanyintolu salaye pe ọkọ akẹru naa to kun dẹnu, ti nọmba rẹ jẹ LSD 611 XU, ti wọn ko mọ ẹru to wa ninu rẹ, lo sọ ijanu rẹ nu lasiko to n sare asapajude.

Ọga agba LASEMA ni sọrọ̀ yii tun kan awọ̀n ọlọkada mẹta pẹlu.

Image copyright LASEMA

Ọsanyintolu fikun pe ni kete ti awọn osisẹ Lasema de ibi isẹlẹ naa, ni awọn ti gbe awọn eeyan to farapa nibẹ lọ sile iwosan, ti awọn ko si ti mọ iru eeyan ti ọkunrin meji to gbẹmi mi ninu isẹlẹ naa, jẹ.

O ni gbogbo ẹ́ru ti wọn ko nibi isẹlẹ naa ni wọn ti fa le agọ ọlọpaa to wa ni Owutu lọwọ.