Yollywood: Lizzy Anjorin tí fi ìwé ìpẹ̀jọ́ ránsẹ́ sí Toyin Abraham

Toyin Abraham Image copyright Toyin Abraham

Lizzy Anjorin ti fẹsun kan Toyin Abraham pe o nlo oogun oloro cocaine lati fi sara rindin, eleyii to lodi sofin.

Lizzy sọ eyi lori ikanni Instagram rẹ, lẹyin to fi iwe ipẹjọ to fi ransẹ si Toyin a han si ori ayelujara.

Ninu iwe ipẹjọ naa, Lizzy fẹsun ibanilorukọjẹ kan Toyin, ati wi pe awọn ololufẹ rẹ n dunkoko mọ oun.

Bakan naa, Lizzy fẹsun kan Toyin wi pe o parọ mọ oun, pe oun gbe oogun oloro, eleyii ti o ni yoo jẹ ki ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro lorilẹede Naijiria, NDLEA ko iwe iransẹ si oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionUnicycle School: Olùdarí ibùdó ìkẹ́kọ̀ kẹ̀kẹ́ alájọwà ń fẹ́ ìrànwọ́ ìjọba

Amọ, o ni awọn mejeeji ni Ajọ Ndlea yoo se iwadii, eleyii ti yoo fihan wi pe Toyin n lo oogun oloro cocaine.

Ija laarin gbajugbaja osere tiata mejeeji yii, ti mu ọpọlọpọ arinyanjiyan dani, ti awọn adari ni Nollywood naa si sọ wi pe awọn yoo pari aawọ laarin awọn mejeeji.

Lizzy Anjorin fèsì padà, ó ní ìsọ̀ alágbo ni Toyin Abraham bímọ sí, kìí ṣe London

Kaka ki ewe agbọn dẹ lori aawọ to n waye laarin Toyin Abraham ati Lizzy Anjọrin, ko ko ko lo tun n le si.

Idi ni pe Lizzy tun ti gbe fọnran aworan kan sita lọjọ Aje, to si n tẹnumọ pe ọmọ ale ni Toyin bi o tilẹ jẹ pe agbẹjọro Toyin ti kan si lati dẹkun iwa ibajẹ Toyin to n se lori ayelujara.

Ninu fonran aworan naa ti Lizzy fi soju opo Instagram rẹ lo ti sọ pe Toyin Abraham kii ran awọn ololufẹ rẹ lọwọ ati awon akẹgbẹ rẹ ninu isẹ tiata.

Lizzy ni ko yẹ ki Toyin maa lo ọpọ ero to jẹ ololufẹ rẹ lati maa fi kọju ija sawọn osere ẹgbẹ rẹ, amọ n se lo yẹ ko maa lo wọn lati ran awọn ti ebi n pa ninu isẹ tiata lọwọ.

Osere tiata naa tun fikun pe, ile alagbo ọmọ ni Toyin bi ọmọ rẹ tuntun si, to si wa nibẹ fun odidi fun ọjọ mẹwa gbako, amọ to ni Toyin n parọ pe ilu London lo bimọ si fun araye.

O fikun wi pe, aworan lasan ni Toyin lo, lati fi parọ wi pe ilu Oyinbo ni oun ti bimọ, bẹẹ lo si ls ya asọ lo lati fi ya fọto, pẹlu afikun pe irọ nla ni Toyin maa n pa, to si ti di ẹni ijakulẹ.

Image copyright Lizzy Anjorin

Lizzy wa n fọwọ gbaya pe oun kii se ẹgbẹ Toyin rara nitori ti kii ba se pe awọn dijọ n se ere tiata ni, Toyin ko ba maa kọ lẹta to mẹwa, ko to lee fi oju kan oun.

"Se emi ati ẹ wa ninu ẹgbẹ ni, so ti kọ ile ni abi o ti ra mọto, iwọ wa n sọ pe mo n jowu awọn aseyọri rẹ, isẹ tiata ko fẹ abosi, abosi maa n tẹ eeyan mọlẹ ni."

Bakan naa lo fikun wi pe, ọmọọmọ ni ọmọ Toyin jẹ si oun nitori oun kii se ẹgbẹ rẹ, bi awọn tilẹ jọ n wọ sokoto kan naa bii ẹgbẹ

Lizzy fẹsun kan Toyin wi pe kii ran awọn eniyan lọwọ, amọ oun ti ri daju wi pe awọn eniyan se oriire labẹ oun, ti wọn si di ẹni iyi ni awujọ.

Image copyright Toyin Abraham

Agbẹjọrò Toyin Abraham kọ̀wé sí Lizzy Anjorin, ó fẹ́ kó ṣe ohun mẹ́ta kí ìjà leè tán

Gbajumọ osere tiata, Toyin Abraham ti mu ileri to se lọjọ Aiku sẹ pe, oun yoo bẹrẹ igbesẹ ofin lori awọn ibajẹ oun ti akẹẹgbẹ rẹ lagbo osere tiata lobinrin, Lizzy Anjorin n se lẹnu ọjọ mẹta yii loju opo Instagram.

Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin naa wa fun yin pe aawọ ati itahun sira ti n waye laarin awọn obinrin osere tiata mejeeji naa, ti Toyin si ti kede pe awọn agbẹjọro oun yoo kan si Lizzy loni ọjọ Aje.

Lọwọ-lọwọ bayii, awọn agbẹjọro Toyin Abraham ti kan si Lizzy bayii, ti wọn si n beere pe ko gbe igbesẹ mẹta pere lati pẹtu si aawọ naa, bi bẹẹ kọ, ọrọ naa yoo de ile ẹjọ.

Image copyright Lizzy Anjorin

Toyin Abraham, nigba to n fi lẹta naa si oju opo Instagram rẹ, tun kede lẹẹkan si pe "kii dara ki eeyan dakẹ nigba miran, nitori dipo ki eeyan ba maa ba ẹlẹdẹ jijagudu, o kuku dara ki eeyan jẹ ko mọ pe in akamọ ni ile rẹ."

Toyin ni oun ko ni sọrọ lori isẹlẹ naa mọ, nitori ikọ alakoso ati awọn agbẹjọro oun ti gba ọrọ naa .

Ninu lẹta naa ni wọn ti n beere pe ki Lizzy lọ pa gbogbo ohun ibajẹ to kọ nipa Toyin rẹ lẹyẹ o sọka, ti wọn si tun n beere pe ko kọ iwe ẹbẹ si ileesẹ amofin naa ati Toyin Abraham, eyi ti yoo safihan pe o ti tuuba.

Awọn agbẹjọro Toyin salaye pe ọpọ nkan ti Lizzy kọ nipa onibara awọn naa lo wa lati baa lorukọ jẹ, ti ko ba si tete tọrọ aforijin, ko si pa awọn ọrọ ibajẹ naa jẹ, ọrọ ọhun yoo beere fun atilẹyin ofin nile ẹjọ.