Oyo Tribunal: Mákindé ní àṣeyọrí òun nílé ẹjọ́ jẹ́ otítọ́ tó lékè irọ́

Seyi Makinde Image copyright Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti juwe aṣeyọri ẹgbẹ PDP nile igbẹjọ to n risi ọrọ idibo gẹgẹ aṣeyọri otitọ to leke irọ.

Gomina naa lo dupẹ lọwọ awọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ fun aduroti wọn, nigba idibo ati lẹyin idibo naa, to si parọwa si ẹgbẹ alatako, APC lati fọwọsowọpọ pẹlu oun lọna lati jumọ gbe ipinlẹ Ọyọ de ebute ogo.

Makinde lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan ti alukoro rẹ, ọgbẹni Taiwo Adisa buwọlu, o ni "imọran mi fun ẹgbẹ APC ni pe, ki wọn gbe oṣelu ti sẹgbẹ kan, a le pada bẹrẹ eto oṣelu lọdun 2022. Nibayi na, ẹ jẹ ka sowọpọ fun itẹsiwaju ipinlẹ Ọyọ."

Gomina Makinde tun tẹ siwaju pe "A fẹ dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ọyọ fun aduroti wọn ki a to dibo, nigba idibo ati lẹyin idibo. Mo mọriri atilẹyin awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ fun igbagbọ wọn ninu wa, a maa tẹsiwaju lati sin yin tọkantọkan."

Image copyright Seyi Makinde

Bẹẹni ni gomina ọhun tun fi ẹmi imore han loju opo Twitter rẹ pe otitọ ni yoo ma leke lọjọkọjọ.

Bakan naa ni ẹgbẹ PDP ti ki gomina ọhun ku oriire, fun bi igbimọ olugbẹjọ to n gbọ awuyewuye ibo gomina nipinlẹ Ọyọ ṣe fi ountẹ lu pe oun ni ẹni to jawe olu bori ninu idibo ipinlẹ naa.

Ẹgbẹ naa yin Makinde fun akitiyan rẹ lati tun ipinlẹ Ọyọ ṣe, ti wọn si tun rọ lati ma bojuwẹyin ninu afojusun rẹ lati mu aye dẹrun fun awọn olugbe ipinlẹ Oyọ.