Ṣé ìwọ leè wa kẹ̀kẹ́ lórí ìgò? Wo bí àwọn ọmọ yìí ti ń ṣe é.
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Unicycle School: Olùdarí ibùdó ìkẹ́kọ̀ kẹ̀kẹ́ alájọwà ń fẹ́ ìrànwọ́ ìjọba

Nigba ti ọlaju kọkọ de silẹ Yoruba, kẹkẹ ologeere lo gbajumọ ti awọn eeyan si mọ dunju, amọ lode oni yii, ilana kẹkẹ wiwa kan tun ti de, eyi to n mu owo wa fun ni.

Kẹkẹ alajọwa ni wọn n pe, eyi to jẹ itẹwọgba bayii laarin awọn ọdọ, ti wọn fi n da awọn eeyan kanka laujọ lọla, koda, ileẹkọ nipa rẹ gan ti wa.

Nigba to n sọrọ lori agbekalẹ ibudo ikẹkọ kẹkẹ naa fun BBC Yoruba, Lekan Kuyoro tii se oludari ibudo naa ni, bii ere, bii ere lawọn n fi kẹkẹ sere nigba to bẹrẹ, ti awọn ko si mọ rara pe ọjọ iwaju rere yoo wa fun ere naa.

O ni o ti di itẹwọgba bayii nitori ko wọpọ laarin awọn eeyan dudu tẹlẹ, to si wa n beere iranwọ ijọba fun ipese ibudo ti awọn yoo ti maa se idanilẹkọ nitori ibi ti awọn wa bayii ko ni aabo to.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko abẹwo BBC sibi idanilẹkọ awọn ọdọ to n se kẹkẹ alajọwa naa, a ri ti wọn n fi kẹkẹ rin lori igo ti wọn to silẹ, eyi to wu ni lori.

Ẹyin naa ẹ wo fidio yi, ori yin yoo wu pupọ nipa awọn ọdọ naa.