Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Jide Kosọkọ ní ìbàjẹ́ ni Lizzy àti Toyin fi n ṣe ayọ̀

Bọlaji Amusan ta mọ si Mr Latin Image copyright mr latin 1510

Aarẹ apapọ fun awọn osere tiata lede Yoruba Tampan, Bọlaji Amusan taa mọ si Mr Latin, ti kesi awọn araalu pe ki wọn yee sẹ epe fun awọn agba osere ninu isẹ tiata.

Bakan naa lo ni ko yẹ ki wọn maa pe wọn ni agbaaya pe wọn ko ri nkan se si aawọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ wọn, lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ kan ba n tahun si ara wọn lori itakun agbaye.

Latin, ninu fọnran aworan kan to fisita loju opo Instagram rẹ lori aawọ to n waye lori ayelujara laarin awọn osere tiata obinrin meji, Toyin Abraham ati Lizzy Anjọrin, o salaye pe, o yẹ ki awọn araalu kọkọ beere lati mọ boya ọmọ ẹgbẹ Tampan ni awọn osere to n ja naa.

Latin ni ẹgbẹ osere tiata pin si orisirisi, ti ọpọ osere kii si se ara ọmọ ẹgbẹ awọn, nitori naa lo se loju ohun ti awọn agba osere lee da si, bi o tilẹ jẹ pe awọn lee da si bii agba osere.

Amọ o ni ti awọn osere naa ba ni awọn kii se ọmọ ẹgbẹ awọn, ti wọn ko si gba imọran si awọn lẹnu, o loju ohun ti awọn lee se.

Latin ni" A n gbiyanju agbara wa, gẹgẹ bii baba, gẹgẹ bii aarẹ ati gẹgẹ bii agba osere lati dẹkun rogbodiyan laarin awọn osere tiata lori itakun agbaye, ko si yẹ ki awọn araalu ro pe awọn kan dakẹ, lai se ohunkohun nipa aawọ naa."

Latin ni ọmọ ẹgbẹ Tampan nikan lawọn lee pasẹ fun lati sinmi agbaja, osere ti kii ba si se ọmọ ẹgbẹ awọn, o loju asẹ ti awọn lee pa fun, awọn kan lee parọwa fun ni.

Aarẹ apapọ fun ẹgbẹ Tanpan naa wa fọwọ gbaya pe awọn n gbe igbesẹ to lagbara bayii lati pinwọn wahala to n waye naa, ti yoo si jẹ rodo, lọ ree mu omi laipẹ.

Image copyright jidekosoko

Bakan naa, agba ọjẹ ninu ẹgbẹ osere Nollywood, Jide Kosoko ti ni ẹgbẹ awọn maa wa ọna abayọ si aawọ to wa laarin Toyin Abraham ati Lizzy Anjorin.

Kosoko sọ fun BBC Yoruba bẹ ẹ lasiko to n fesi si bi Toyin Abraham se dunkooko pe oun yoo gbe Anjorin lọ si ile ẹjọ, lẹyin t o sọ wi pe Anjorin fi orukọ oun yi ẹrẹ, ti wọn si tahun si ara wọn.

O fi kun wi pe ori ẹrọ ayelujara ni oun ti ri iroyin naa, amọ ẹgbẹ awọn yoo pe awọn mejeeji lati pẹtu si aawọ to wa laarin wọn.

Image copyright mamarainbowofficial

Ninu ọrọ rẹ, Mama Rainbow naa ni oun ko mọ nkankan nipa isẹlẹ naa, ti ko si si ẹnikẹni to fi ọrọ naa lọ oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mama Rainbow fikun pe, oun ko kopa ninu fiimu kankan mọ, nitori wọn kọ lati lo oun, ati wi pe Ọlọrun lo n lo oun bayii.