Saudi Arabia oil attack: Buhari ní ojú Nàìjíríà ti rí ohun tí Saudi Arabia ń rí báyìí

Aarẹ Muhammadu Buhari Image copyright Getty Images

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe, igba ipọnju la n mọ ọrẹ, ti orilẹede Naijiria si wa pẹlu ijọba atawọn eeyan Saudi Arabia, lori ikọlu awọn ibudo ifọpo rẹ to wa ni Khurais ati Abqaiq.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ Buhari ṣalaye ọrọ yii ninu atẹjade kan, eyii ti amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin Garba Shehu fi sita.

Buhari ni lootọ lawọn oniṣẹ ibi to wa nidi ikọlu naa ko fi oju han sita, sibẹ ohun kan to foju han ni pe, ikọlu eto ọrọ aje naa ni awọn oṣiṣẹ laabi naa fi n dojukọ ijọba atawọn ọmọ Saudi Arabia.

Image copyright Getty Images

O tẹsiwaju pe, ko si aniani pe wọn fẹ fi doju jijẹ-mimu awọn olugbe orilẹede naa, ti ko mọwọ tabi mọ ẹsẹ ninu eredi ikọlu naa bolẹ ni.

"Awa pẹlu lorilẹede Naijiria ti foju wina irufẹ ikọlu bayii lori ibudo epo rọbi wa. Gbogbo awọn to ro wi pe nipa ṣiṣe bẹẹ awọn lee doju iṣẹ ijọba bolẹ,, ko mu erongba wọn ṣẹ nigba naa, tabi nigbakugba."

Aarẹ Buhari ni ko si ẹnikẹni lawujọ agbaye ti yoo to si ẹyin awọn to ṣe ikọlu naa, ẹni yoowu ti wọn lee jẹ tabi idaniloju wọn ninu ohun gbogbo ti wọn n gbe ṣe.