Osun Accident: Agbegbe Gádà ní ìlú Ẹdẹ ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé

Aworan to ja bọ sinu omi Image copyright Getty Images

Eeyan mẹta lo jade laye lalẹ ọjọ aiku ni ilu Ẹdẹ nipinlẹ Ọṣun nigba ti ọkọ bọọsi ti wọn wa ninu rẹ, jabọ sinu odo Ọṣun ni agbegbe Oke-gada ni ilu Ẹdẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni aisi ikọ adoola ẹmi lasiko, lo ṣokunfa iku awọn eeyan naa.

Bakan naa, ni awọn eeyan ti isẹlẹ naa soju wọn salaye pe ohun jijẹ lo kun inu ọkọ naa lasiko ti o fi re bọ sinu odo naa.

Nnkan bi agogo meje alẹ ni wọn ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awakọ bọọsi naa n gbiyanju lati yẹra fun awọn koto to wa kaakiri oju popo naa.

Amọṣa, wọn ni ko si iranwọ lati doola ẹmi wọn titi di nnkan bii agogo mọkanla alẹ, afi igba ti awọn eeyan kan fi dide lati doola wọn.

Sugbọn dokita ileewosan ti wọn gbe wọn lọ ni oku ni wọn gbe wọn wọ ileewosan naa.