Champions league: Chelsea gbélé fọrùn rọ́ ní Stamford Bridge, àwìn ni Valencia fi ṣẹ Lampard lọ́wọ́

Agbabọọlu Chelsea ṣubu silẹ, agbabọọlu Valencia kan fẹ ṣubu lee Image copyright Getty Images

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea joye gbele forunrọ lalẹ ọjọ iṣẹgun nigba ti wọn gbalejo ẹgbẹ agbabọọlu Valencia ni idije Champions league.

Chelsea yoo maa pada si agbami bọọlu Champions league lẹyin ti wọn fi saa ọdun to kọja gba bọọlu ni agbami Europa. Amọṣa ipadabọ naa ko so eso rere ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ọdẹdẹ Chelsea ni Stamford Bridge ni ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye, ko gbe Tammy Abraham atawọn ọmọ ikọ Frank Lampard yooku.

Rodrigo, ọmọ Valencia lo da okuta si gaari Lampard ninu ifẹsẹwọnsẹ rẹ akọkọ ni idije Champions league gẹgẹ bii olukọni Chelsea.

Image copyright Getty Images

Iṣẹju kẹrinlelaadọrin ni ifẹsẹwọnsẹ naa wa nigba ti Rodrigo fi gba bọọlu sinu awọn Chelsea.

Eyi ti ko ba tun duro gẹgẹ bii itunu fun Chelsea ni igba ti alamojuto ere naa fun fere fun pẹnariti, iyẹn gbe e silẹ ko gba a si sawọn ṣugbọn igbo rere ni Barkley agbabọọlu Chelsea to gba a gba a si.