Champions League: Balógun ní England, akéwejẹ̀ ní Italy, Liverpool yọ̀ ṣubú níwájú Napoli pẹ̀lú àmì ayò méjì sí òdo

Sadio Mane, agbabọọlu Liverpool kawọ bo oju Image copyright Getty Images

Lọwọ yii, lara awọn ikọ agbabọọlu ti o n gbana jẹ ni Liverpool wa. Yatọ si pe oun ni ẹgbẹ agbabọọlu ti ife ẹyẹ Champions League wa lọwọ rẹ ni lọwọlọwọ, ohun nikan ni ẹgbẹ agbabọọlu ti ko tii sọ ami kankan nu ni gbogbo idije liigi ti saa yii.

Nitori naa, ireti ọpọ ni pe ẹran ijẹ ni wọn yoo fi Napoli ṣe ninu ifẹsẹwọnsẹ Champions league to waye ni alẹ ọjọ Iṣẹgun laarin Napoli ati Liverpool, ṣugbọn ọr ko ri bẹẹ rara fun wọn.

Image copyright Getty Images

Napoli to gbalejo ifẹsẹwọnsẹ naa jẹwọ pe awọn kii ṣe ọmọ ale nile awọn nigba ti wọn fi ami ayo meji gbo ewuro si oju Salah, Mane atawọn akẹgbẹ wọn.

Gbee silẹ koo gba sile, iyẹn pẹnariti ti Dries Merten kọkọ gba wọle ni Napoli fi ṣide iya fun Liverpool nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejilelọgọrin ki Llorente to fọba lee ni igba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ku dẹdẹ ko pari.