Fayoṣe: Gómìnà Fayemi kò nílò ẹjọ́, torí àti ṣe ohun ti ìjọba àná kò leè ṣe ní wọ́n fi dìbò fún un

Fayemi ati Fayose n bọwọ Image copyright Getty Images

Gomina Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti ti fi ẹsun kan iṣejọba ana ni ipinlẹ naa labẹ Ayọdele Fayose pe biliọnu mẹtadinlọgọta lo jẹ awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bii owo oṣu ati ajẹmọnu gbogbo.

Amọṣa, Fayoṣe pẹlu ti da esi pada pe, ariwo lasan ni Fayẹmi n pa ati pe iṣẹ ni awọn eeyan ipinlẹ Ekiti yan an lati wa ṣe kii ṣe ariwo.

Nibi ipade kan pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba nilu Ado Ekiti ni gomina Fayẹmi ti kede ọrọ naa. O ni iṣejọba oun n sa ipa gbogbo to yẹ lati san awọn ajẹẹlẹ owo oṣu ati ajẹmọnu naa.

O ni segesege lori ilana sisan owo oṣu naa lo ṣokunfa bi o ti ṣe wa di oke nla niwaju ijọba bayii.

Fayẹmi ni ajẹsilẹ owo oṣu naa wa laarin ọdun 2014 si oṣu kẹwa ọdun 2018.

Nigba ti o n dahun loju opo twitter rẹ, Gomina ana, Ayọdele Fayoṣe ni iyalẹnu ni ọrọ ti Fayẹmi sọ jẹ fun oun ṣugbọn o ni oun "rọ ọ lati san owo oṣu oṣiṣẹ nitori eredi ti araalu fi dibo yan an ni lati ṣe oun ti oun ko lee ṣe"