Ohun tí kò ṣẹlẹ rí ní gbẹ òṣìṣẹ ń gbé wọ ọrọ owó oṣù tí wọn ń jà fún- Pa Sunmọnu, ààrẹ àkọ́kọ́ fún ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Minimum wage: Ọ̀hun ni àwọn òṣìṣẹ́ ìpele 9 si 17 ń béèrè fún lórí ẹ̀kúnwó òṣìṣẹ́ N30,000

"Ohun tí kò ṣẹlẹ rí ní ẹgbẹ òṣìṣẹ ń gbé wọ ọrọ owó oṣù tí wọn ń jà fún", gẹgẹ bi alagba Sumonu ṣe sọ ọ.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ti n sọ pe awọn yoo tun ti iloro awọn ileeṣẹ pa laipẹ bi awọn to ba mọ ijọba apapọ ko ba tete pe e nibi to ti n gbọrọ lati tete wa nkan ṣe si ibeere ẹgbẹ oṣiṣẹ lori sisan owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ.

Amọṣa o, agba ọjẹ kan ninu ijijagbara ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, Alagba Hasan Sunmọnu ti da awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹkun pe ohun ti ko si ninu iwa ati iṣe ẹgbẹ oṣiṣẹ ni wọn n rawọ le.

Alagba Sunmọnu ni aarẹ akọkọ fun ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ lori ẹrọ ibanisọrọ, Alagba Hassan Sunmọnu ni ijiroro ẹkunwo oṣu fun oṣiṣẹ to ba kere julọ lẹnu iṣẹ ọba kii kan awọn agba oṣiṣẹ gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ti n ṣe bayii.

Alagba Sunmọnu ni ni igba iwaṣẹ bi ẹgbẹ oṣiṣẹ ba n ja fun ẹkunwo oṣu to kere julọ, awọn oṣiṣẹ ni ipele kini titi de ipele ikẹfa si ikeje ni ọrọ atunto owo oṣu maa n kan.

"Ohun to ya mi lẹnu ni bi awọn oṣiṣẹ onipele kẹtadinlogun tun ṣe n beere fun atunto yii, ko de ọdọ wọn."

Image copyright Getty Images

Alagba Sunmọnu tun ṣalaye siwaju sii pe o ni ohun ti o maa n kan gbogbo ipele oṣiṣẹ naa ni ti ijọba ba fẹ tun owo oṣu gbogbo oṣiṣẹ lapapọ to.

O ni ọhun ni awọn agba oṣiṣẹ to n beere fun ki sisan atunto ọgbọn ẹgbẹrun naira owo oṣu tuntun naa o de ipele awọn fẹ jẹ nitori wọn ko ba awọn ojẹ wẹwẹ oṣiṣẹ to ja fun owo oṣu tuntun naa jiya nigba ti wọn n jijagbara fun un.

Igbimọ ijiroro lorukọ Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni wọn ti fi itupalẹ bi wọn yoo ṣe san ọgbọn ẹgbẹrun naira owo oṣu tuntun to kereju naa to ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ati NLC si leti .

Ni ọjọ kejidinlogun oṣu kẹrin ọdun yii ni aarẹ Buhari buwọlu abadofin lori sisọ ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira di owo oṣu oṣiṣẹ to jkere julọ lorilẹede Naijiria.