Champions league: Real Madrid jẹ wábiwọ́sí ìyà lọ́wọ́ PSG, Di Maria ló hun pàṣán ìyà wọn

Awọn agbabọọlu PSG ati olukọni wọn Image copyright Getty Images

Ode ko dara fun olukọni ikọ agbabọọlu Real Madrid, Zinedine Zidane atawọn agbabọọlu rẹ ni alẹ Ọjọru nigba ti wọn lọ koju Paris St-Germain ni idije Champions League.

Ko si si ẹni meji to doju ọla Real Madrid bolẹ bikoṣe Angel di Maria, agbabọọlu rẹ nigbakan ri ṣugbọn to ti darapọ mọ PSG bayii.

Iṣẹju kẹrinla ati ikẹtalelọgbọn ifẹsẹwọnsẹ naa ni Di Maria gba bọọlu sawọn ki Meunier to fsba lee nigba ti idije naa wọ aadọrin iṣẹju.

Nnkan ko tii fi bẹẹ ṣe ẹnure fun Zidane lati igba ti o ti pada de lẹẹkeji gẹgẹ bii olukọni fun Real Madrid.

Saa marun ni Angel di Maria lo ni Madrid ki o to gbe igba bọọlu agbajẹun rẹ lọ si PSG lorilẹede France.

Image copyright Getty Images

Lẹyin o rẹyin goolu mẹta ti ko labula ni wọn fi na Real Madrid.

Lẹyin ti gbajugbaja agbabọọlu ni , Christiano Ronaldo ti fi Real Madrid silẹ ni ọdun 2018 ni nnkan ti dẹnukọlẹ fun Real Madrid.