Champions league: Athletico bomi paná ayọ̀ Juventus ní ìpadàbọ̀ Ronaldo sí ìlú Madrid

Ifẹsẹwọnsẹ Athletico ati Juventus Image copyright Getty Images

Idunnu kọkọ ṣubu layọ fun Christiano Ronaldo atawọn akẹgbẹ rẹ ni Juventus nigba ti wọn kọkọ gba goolu meji wọle sinu awọn Athletico Madrid nibi ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin wọn lalẹ ọjọ iṣẹgun nibi idije Champions league.

Amọṣa ayọ naa ko pẹ pupọ pẹlu bi Athletico ṣe jẹwọ ọmọ ọkọ fun wọn pẹlu goolu meji ni ṣiṣẹ n tẹle.

Agbabọọlu ikọ Chelsea tẹlẹ, Juan Cuadrado lo kọkọ gba gooolu wọle fun Juventus ki Blaise Matuidi to fi ori gbe ikeji wọle fun goolu Juventus keji.

Amọṣa, Stefan Savic ati Hector Herrera lo ra igba pada fun Athletico Madrid.

Ọmi ti wọn ta naa mu ki Athletico Madrid ṣi ni igberaga lati sọrọ pe ko si ẹgbẹ agbabọọlu to tii fi ẹyin wọn balẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹwaa ti wọn ti gba sẹyin nile wọn ni papa iṣire Blaise Matuidi.