Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèré tíátà fa ìbínú yọ

Mr. Latin and Yinka Quadri

Oríṣun àwòrán, MRLATIN

Awọn agbaagba ẹgbẹ oṣere tiata Yoruba ti jawe joko jẹẹ le Lizzy Anjọrin ati Toyin Abraham, awọn oṣere meji ti wọn n tahun si ara wọn lati bi ọjọ mẹta bayii lori ikanni ayelujara.

Wọn kilọ pe àwọn kò ní fi àyè sílẹ̀ fún òṣèrè tíátà kankan láti dójú ti ẹgbẹ́ mọ.

Ede aiyede laarin awọn oṣere mejeeji yii bẹrẹ nigba ti iroyin jade sita pe Toyin Abraham to ṣẹṣẹ bimọ laipẹ yii kọ lẹta ipẹjọ si Lizzy eleyi to mu ki Lizzy pẹlu gbana jẹ. Lẹyin eyi ni ọrọ naa wa di fa-ki-n-fa laarin awọn mejeeji.

Lẹyin ọpọ awuyewuye, ipẹtu si alaafia laarin awọn mejeeji, ti o si jẹ pe kaka ki ewe agbọn ọrọ naa dẹ, lile lo tun n le sii, awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣere tiata Yoruba ti wa paroko "Ẹ sinmẹdọ ranṣẹ si awọn mejeeji atawọn oṣere miran ti wọn ba ni iru rẹ lọwọ tabi lọkan.

Ninu fọnran fidio kan ti wọn fi sita, aarẹ ẹgbẹ oṣere tiata Yoruba Ọgbẹni Bọlaji Amuṣan ati ọkan lara awọn agba ọjẹ ninu ere tiata lorilẹede Naijiria, Alhaji Yinka Quadri ti ti paṣẹ ki gbogbo awọn mejeeji lọ ree gbẹnu dakẹ tabi ki wọn fi kele ẹgbẹ gbe wọn.

Nibayii awọn ololufẹ awọn oṣere tiata mejeeji ti n kan sara si igbesẹ naa eleyi ti wọn ni o tọna lati mu alaafia ati irẹpọ jọba laarin ẹgbẹ naa.