Xenophobia: Ọrò ajé llè South Africa ti ń rẹ̀yìn lọ́wọ́lọ́wọ́

Allen Onyeama Alaṣẹ Ọkọ̀ Ofúnrufu Air Peace

Alaga ati Oludari ọkọ Ofurufu Air Peace Allen Onyeama, ti ṣalaye pe Ijọba ilẹ South Africa ni imọlara awọn ọmọ Nigeria ni orilẹede wọn.

O ni inu orilẹedẹ ko dun pe ki awọn ọmọ Naijiria kuro nibẹ rara.

Ninu alaye to ṣe pẹlu ikọ ile iṣẹ BBC l'ọjọ Abamẹta lo ti sọ pe, ijọba ilẹ naa ko fẹ ki awọn ọmọ Naijiria lọ nitori pe o ṣe akoba fun ọrọ aje wọn.

Bakan naa lo ni ko din ni ẹedẹgbẹta awọn ọmọ ilẹ yii to ṣi ku si orilẹede naa to fẹ wale sugbọn ti gbogbo eto ati da wọn pada wale ṣi ku diẹ.

O ni igba akọkọ ree ti wọn maa yẹ oun si julọ ni igbesi aye oun ti inu oun si dun ju laye.

Onyeama wi pe lọwọlọwọ yii, eto ọrọ aje ilẹ South Africa ti n mẹhẹ latari ipa pataki ti awọn ọmọ Naijiria n ko ni ilẹ naa.

Bakan naa ni ko ṣai mẹnu ba Papakọ Ofurufu ilu Enugu pe, yoo fa ijamba nla ti ijọba apapọ ko ba tete bo ju to.

O ni papakọ Ofurufu naa lo ti wa ni ipo ẹlẹgẹ bayii ti ko si dara to fun fifo ọkọ ofurufu.

Gẹgẹ bi o ti wi, o ni ki ijọba apapọ tete mura si atunṣe papakọ naa ki iṣẹ si bẹrẹ ni pẹrẹwu.

Ni tirẹ, Ọgbẹni Allen Onyeama ni ọkọ baalu oun yoo ṣi pada lọ si orilẹede South Africa lati ko awọn ọmọ Naijiria to ba ṣi nifẹ lati pada wa sile.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌyàtọ̀ tó wà láàrin ìṣesí Nàìjíríà àti South Africa