Ìrọ̀rùn ló bá dé fún mi láti bú Àarẹ Buhari -Sisi Quadri
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri

Sisi Quadri ni ile loun ti ba eebu bibu.

Quadri Oyebamiji ni orukọ ongbontarigi adẹrin pa oṣonu ninu sinima agbelewo Yoruba ti gbogbo eeyan mọ si Sisi Quadri.

O ṣalaye kikun nipa ara rẹ ati bo ṣe bẹrẹ ere tiata fun BBC Yoruba.

Omọ ilu Iwo olodo Ọba nipinlẹ Ọṣun yii sọrọ nipa didagba rẹ ati ipa ti awọn obi rẹ ni lori iṣẹ rẹ.

Bakan naa ni Sisi Quadri gba awọn ọdọ Naijiria ni imọran lori ọjọ iwaju wọn lati tẹpa mọ iṣẹ.

Ni afikun, Sisi Quadri dahun ibeere to n jẹ ọpọ ololufẹ rẹ lọkan lori bo ṣe maa n ṣe bi obinrin ninu sinima Yoruba.

Ẹlẹekẹ eebu alawada yii to jẹ atọkun eto to tun n ṣiṣẹ alaga iduro nibi idana igbeyawo yatọ si iṣẹ ere ṣiṣe naa ni ko si ọjọ iwaju fun ọlẹ rara.