Premier league: Manchester United jẹ àjẹkún ìyà góòlù méjì lọ́wọ́ Westham United

Westham ati Man United Image copyright Getty Images

Ọwọ iya ba Manchester United ni ile Westham United ni ọjọ Aiku nibi idije Premiership ilẹ Gẹẹsi.

Irinajo ti ko lọpẹ ninu ni olukọni iks Manchester United, Ole Gunner Solkjaer ko awọn agbabọọlu rẹ rin lọ si papa iṣire....to jẹ ibuba Westham united nibi ti wọn ti lu wọn ni goolu meji sodo.

Image copyright Getty Images

Pẹlu Esi yii, o fihan pe ifẹsẹwọnsẹ meji pere ni Manchester united ṣi bori bayii ni mẹfa ti wọn gba bayii ni saa yii.

Andriy Yarmolenko lo kọkọ gba goolu alakọkọ wọle fun Westham ki Aaron Cresswell to fọba lee nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinlelọgọrin.

Lọwọ yii idi olukọni wọn n gbona bayii pẹlu ironu igbesẹ ti awọn alaṣẹ ẹgbẹ agbabọọlu naa lee gbe bi nnkan ko ba ṣe ẹnuure funwọn laipẹ.

Related Topics