English Premier league: Liverpool gun Chelsea bí ẹṣin lójúde rẹ̀ ní Stamford bridge

Awọn agbabọọlu Chelsea ati Liverpool

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn agba bọ wọn ni bi ale iya ẹni ba ju baba ẹni lọ, baba laa pe.

Bẹẹ lọrọ ri fun Chelsea nigba ti wọn gbalejo Liverpool ni ifẹsẹwọnsẹ kẹfa, saa idije liigi ti ọdun yii ni ilẹ Gẹẹsi.

Trent Alexander-Arnold lo kọkọ gba goolu wọle fun Liverpool nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinla ki Roberto Firmino to dee lade funwọn.

Amọṣa lẹyin ọpọlọpọ jija raburabu, Ngolo Kante da ẹyọ kan pada fun Chelsea.

Gbogbo akitiyan atamatase Chelsea, Tammy Abraham lati yọ ikọ rẹ jade ninu ọfin Liverpool lo ja si pabo.

Pẹlu esi yii, ifẹsẹwọnsẹ meji pere ni Chelsea ṣi bori ninu mẹfa ti wọn ti gba ninu liigi saa yi labẹ akoso olukọni wọn tuntun, Frank Lampard.

Esi yii si n fi Liverpool silẹ loke tente tabili liigi ilẹ Gẹẹsi.

Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu ti gba, Liverpool nikan ni ko tii padanu ifẹsẹwọnsẹ kankan bayii.