English Premier League: Arsenal jẹ́ọ́ àgbò tó tàdí mẹ́yìn fún Aston villapẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta sí méjì

Agbabọọlu Arsenal ati Aston Villa n du bọọlu mọ ara wọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ori lo ko Arsenal yọ lọwọ Aston Vila ni idije Premiership to waye ni papa iṣire Emirates.

Ilẹ kọkọ ṣe bi ẹni fẹ pooyi fun Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ naa nigba ti John mcGinn gba bọọẹu wọle nitori aikiyesara awọn adilemu Arsenal to n woran lẹyin.

Nicolas Pepe gba gbeelẹ koo gba sile, pẹnariti wọle lẹyin ti awọn agbabọọẹu Aston Villa gbe Gendouzi, agbabọọẹu Arsenal lulẹ ninu oju iwọn alapoti

Aston villa ko jẹ ko tutu ti wọn tun ti fi gba omiran wọle.

Lẹyin eyi ni Calum Chambers ati Aubameyang wa gba ayo kọọkan wọle lati bọ ẹwu itiju ti aston villa fẹ da ro Arsenal ni ibuba rẹ kuro.

Pẹlu esi yii, ipo kẹrin ni Arsenal wa lori tabili liigi ilẹ Gẹẹsi bayii pẹlu ami mọkanla.

Ọkan lara awọn agbabọọlu Arsenal, Ainsley Maitland -Niles gba kaadi pupa ti wọn si lee jade nitori ikọlu rẹ si agbabọọẹu Aston Villa kan.