Fàwọ̀rajọ̀, aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ àti ònírọ́ ayé ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé dúkìá wọn sórí ayélujára- Ojopagogo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Yollywood: Ṣàgbẹ̀lójú yòyò, aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré- Ojopagogo

Ibi ori da emi si ni mo n gbe- Ojopagogo.

Fàwọ̀rajà àti ònírọ́ ayé ni ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé dúkìá wọn sórí ayélujára- Ojopagogo

Gbajugbaja agba ójẹ oṣere Yoruba, Razak Olayiwola ti gbogbo eeyan mọ si Ojopagogo ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to n ṣẹlẹ laarin awọn oṣere Yoruba.

O sọrọ ni kikun lori awọn oṣere Yoruba ti wọn n gbe ara wọn sori ayelujara ati awọn ohun ini wọn atawọn to n parọ igbe aye wọn.

Ojopagogo ni ere ṣiṣe a maa parọ mọ eeyan ni oju aye.

O ni awọn ipa olowo ti awọn n ko ninu ere ko sọ pe olowo ni awọn oṣere tiata.

AbdulaRazak ni ko si ohun to buru lati gbe oore Olorun si ojutaye ṣugbọn iwọntunwọnsi ni gbogbo nkan.

Ojopagogo beere ibeere nla pe awọn agba oṣere bii Ogunde, Baba Salah atawọn eekan mii kii ṣe awọn nkan yii.

Agba ọjẹ oṣere yii wa gba awọn oṣere to ku lati ṣe jẹjẹ nitori piparọ lori ayelujara kii jẹ ki eeyan ri alaanu.

O ni ki awọn ọdọ iwoyi rọra sare mọto fi kọlu kẹkẹ lasiko yii.