Boris Johnson: Gbígbé ilé aṣòfin tì pa kùnà, ilé ẹjọ́ pàṣẹ

Àkọlé àwòrán Ìgbẹ́jọ́ lórí gbígbé ilé aṣòfin tì pa

Ile ẹjọ to ga ju ni ilẹ Gẹẹsi ti dajọ pe aba ti alaṣẹ ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson pa lati gbe ile aṣofin ti, kuna.

Ile ẹjọ naa ni ofin ko faaye gba ohun ti Boris ṣe yii rara ti ko si boju mu.

Ogbẹni Johnson paṣẹ̀ lati ti ile aṣofin pa fun ọsẹ marun un ni ibẹrẹ oṣu kẹsan an, ọdun yi, pẹlu alaye pe Obabinrin fẹ sọrọ lori eto ilana tutun ti alaṣẹ naa.

Sugbọn ni bayi, ile ẹjọ to ga julọ ni ilẹ Geesi ti wi pe igbese naa kuna, to si jẹ ohun ti ko tọ lati di ile aṣofin lọwọ nipa ṣi ṣe iṣẹ oojọ wọn.

Aarẹ ile ẹjọ naa, Lady Hale, lo wi pe ''ipa gbese naa lori eto iṣejọba awaarawa ko kere.''

Àkọlé àwòrán Alase ilẹ Geesi

Pataki idajọ yii fun UK ko ṣee fi ẹnu sọ tan lasiko yii nitori eyi tun fidiẹ mulẹ pe ko si ẹni to kọja ofin nilẹ Gẹẹsi.

Eyi fihan pe ibi ko gbọdọ ju ibi lọ koda, ninu iṣelu orilẹ-ede.

Adajọ mọkanla ti wọn gbọ ẹjọ naa fẹnuko pe ko yẹ ki Boris Johnson ti ile aṣofin pa ko si so ijoko ile rọ titi di oṣu kọkanla to kede.

Related Topics