Ise Ekiti Robbery: ìgárá ọlọ́sà ya bo banki,Ọlọ́pàá kàn pàdánù ẹmi rẹ́

Ẹnu ọna ileefowopamọ First Bank, Ido-Ani Image copyright Thenationonline
Àkọlé àwòrán Aworan ile ifowopamọ kan nilu Ido Ani ti awọn ajigunjale yabo laipẹ yi

Awọn adigunjale tun ti ṣoro nipinlẹ Ekiti nibi ti wọn ti yabo ile ifowopamọ kan nibẹ.

Lọsan ọjọbọ ni awọn alọkiolounkigbe yi ṣigun bo ile ifowopamọ Wema ti wọn si pa ọlọpaa to wa nibẹ.

Nigba ti o n fi idi ọrọ yi mulẹ fun BBC Yoruba,alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti,Caleb Ikechukwu ni awọn ajigunjale mẹfa ni wọn ṣiṣẹ yi.

''O ṣeni laanu pe wọn ṣeku pa ọlọpaa kan ṣugbọn yatọ si ọlọpaa yi ko si lomiran to ku ninu iṣẹlẹ naa.''

Eyi ni igba ikeji ti awọn ajigunjale yoo maa ṣe ọṣẹ ni Ekiti laarin oṣẹ mẹta.

Ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin,ọlọpaa mẹta ati awọn eeyan mẹrin miran ko agbakọ lọwọ awọn ajigunjale to yabo ile ifowopamọ kan ni Ilasa Ekiti.

A gbọ pe ado oloro lawọn ajigunjale naa lo lati ja ilẹkun ile ifowopamọ si ohun.

Ọgbẹni Caleb ni awọn n tọ pinpin awọn ajigunjale naa ati pe awọn yoo ri pe ọwọ tẹ wọn laipẹ.