Ìròyìn Kàyééfì BBC Yorùbá: Bí Ọba aládé ṣe jàjà bọ́ lọ́wọ́ àwọn afurasí ajínigbé

Kabiyesi Osi

Lori eto iroyin Kayeefi BBC Yoruba lọsẹ yii, a mu itan nipa bi awọn ajinigbe darandaran ti ṣe fẹ gbiyanju lati ji Ọba Alade gbe nilẹ Yoruba.

Kabiyesi onirẹsi ilu Irẹsini ipinlẹ Ondo, Oba David Olajide ni Oba Alade ti a ba sọrọ ti wọn si tu kẹkẹ ọrọ kalẹ nipa bi awọn Fulani darandaran kan ti ṣe n ṣọṣẹ lagbegbe rẹ.

Ọrọ awọn darandaran to ti fẹ di ọdaran nilẹ Yoruba jẹ ohun ti o n kọ awọn eeyan lominu.

Ẹ wo fidio naa ni ẹkunrẹrẹ ninu fọ́nrán tó wà lókè yìí.