Ondo state: Bàbá ọlọ́mọ méjì kú sínú àgbàrà òjò nílùú Akure

Bata ati ọpa Image copyright Getty Images

Omi ti gbe baba ọlọmọ meji kan lọ nilu Akurẹ lẹyin ti ojo arọọrọda kan rọ lalẹ ọjọ Ẹti.

Iroyin taa gbs ṣalaye pe iṣẹlẹ buruku yii ṣẹlẹ lagbegbe Oke Iyara ni Ijọka.

Nibẹ ni wọn ni arakunrin yii atawọn ẹbi rẹ n gbe ki ọlọjọ to de.

Iṣẹ ọkada wiwa ni wọn sọ pe o n ṣe.

Owurọ ọjọ Abamẹta ni awọn aladugbo to ri oku arakunrin naa nibi ti agbara ojo naa wọ si.

Ohun ti awọn aladugbo rẹ sọ ni pe agbara ojo naa gba arakunrin ọhun ti wọn ni orukọ rẹ n jẹ Idowu Kọmọlafẹ ati alupupu rẹ nigba to n gbiyanju ati gba aarin agbara ojo naa kọja lọ si ile rẹ.