Nigeria independence Day: Kíni àwọn ìpèníjà ẹtọ ààbò ṣáájú òmìnira Nàìjíríà?

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ọmọ ogun 18,000 lo wa ni Naijiria ṣaaju ominira ọdun 1960

Eto aabo jẹ ọkan pàtaki lara iṣoro to n koju Naijiria lasiko yii.

Ola, ọjọ Iṣegun, ọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 2019 ni orilẹ-ede Naijiria a pe ọmọ ọdun mọkandinlọgọta lẹyin ominira.

Lọdun 1960 ni Naijiria gba ominira kuro lọwọ ijọba amunisin ti ilẹ Gẹẹsi.

Titi di asiko yii ipenija eto aabo Naijiria ti n gbẹbọ lọwọ tolori tẹlẹmu.

Bẹrẹ lati ti awọn ajinigbe Ọpẹ́ o! Ìyá Siasia kúrò lákàtà àwọn ajínigbé lẹ́yìn oṣù méjì ààbọ̀, awọn alakatakiti ẹsin Islam Boko Haram, ISWAP ti ṣekú pa òṣìṣẹ́ ẹgbẹ́ aláànù Action Against Hunger titi lọ si ti awọn agbesunmọmi loriṣiiriṣii laiyọ ti awọn fulani darandaran, atawọn adigun jale ti aye n pariwo lasiko yii.

Ogagunfẹyinti Sadiq Garba Shehu, to jẹ ọkan pataki lara awọn to mọ nipa eto aabo Naijiria ṣaaju ominira ba BBC sọrọ lori ipenija lasiko naa.

O ni awọn eniyan Naijiria ko to bayii rara lasiko ominira ati pe, ṣebi bi ori ba ṣe tobi to lo ṣe n fọ olori mọ.

O ni awọn ọlọpaa ati awọn ọmọ ogun ilẹ lo n ṣamojuto eto aabo Naijiria ati awọn olori agbegbe kọọkan.

Ogagunfẹyinti ni: "Lasiko gbigba ominira Naijiria, awọn eeyan bẹru ijọba pupọ.

Wọn bẹru awọn alaṣẹ to n dari wọn fun idi eyi, iwa buruku ko pọ rara.

Ati pe, ifẹ awọn ara ilu wa lọkan koowa, ko sẹni to fẹ ṣe ẹnikeji rẹ nika pupọ.

Ki a to ṣẹṣẹ sọ nipa agbara ofin ati ijiya to tọ si ẹṣẹ fun ẹnikeni perete to ba dẹṣẹ."

Garba Sadiq ṣapejuwe asiko yii pe gbogbo ara ilu lo fẹsọ n gbe igbe aye alaafia ti awọn eniyan si ni itẹlọrun.

O ni ko sẹni to fẹ ki agbara ofin ba oun nitori tonile talejo lo bọwọ fun ofin Naijiria tuntun to ṣẹṣẹ gba ominira.

Ni iwoye rẹ, nkan bii ọdun to wa laarin 1970 si 1980 ni eto aabo Naijiria bẹrẹ si ni yipada.

O ni: bayii, eto ọrọ aje Naijiria ti mẹhẹ ni eyi to n ṣakoba fun eto aabo pupọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Sadiq Garba ni ifẹ lati di ọlọrọ ojiji ati olowo laiṣiṣẹẹ naa tun n ṣakoba fun eto aabo Naijiria lasiko yii.

Ogagunfẹyinti yii ni ojutu si iṣoro to n koju Naijiria lasiko yii ni ki ijọba tun eto ọrọ aje ṣe.

Ati pe ki ijọba fi aja iwoyi maa ṣọ ehoro iwoyi ki awọn ọdọ gbajumọ iṣẹ aje ti ko ni iwa buruku ninu.