Yollywood: Nkan tó pa Ojo pagogo àti Kunle Afolayan pọ̀

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán ẹni ti yoo pẹgan ajanaku laa ni mo ri nkan firi

Ta ni Kunle Afolayan?

Oni, ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan an ọdun 1974 ni ọjọ ibi Kunle Afolayan.

Kunle Afolayan jẹ ọmọ bibi ilu Igbomina ni ipinlẹ Kwara ni aarin gbungbun Naijiria.

O jẹ ọkan lara ọmọ gbajugbaja agba oṣere ni: Ade Love.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Iṣẹ ori ran mi ni mo n ṣe

Adeyemi Josiah Afolayan to jẹ baba Kunle Afolayan bio awọn ọmọ ti wọn yan iṣẹ rẹ laayo ni eyi ti Kunle ti lamilaaka lasiko yii.

O kawe gboye lori imọ ọrọ aje nile iwe giga ni eyi to fi ṣiṣẹ diẹ ni banki ki o to darapọ mọ ere ori itage ṣiṣe ni pẹrẹu ti o si ni imọ lori bi a ṣe n fiimu.

New York Film Academy ni Kunle ti lọ kọ sii nipa fiimu ṣiṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Lati bii ọdun 2005 ni Kunle Afolayan ti bẹrẹ si ni ṣe ere ṣiṣe ti o si ti ṣe ọpọlọpọ ere ti wọn ti gba ami ẹyẹ ti ko lounka.

Ninu awọn ere ti o sọ ọ di ilu mọọka ni ni ere The Figurine: Araromire, ti ede Yoruba ati Phone Swap ni ede gẹẹsi ti Wale Ojo, Joke Silva naa kopa nibẹ.

Lara awọn ẹbi rẹ ti wọn jọ n ṣe iṣẹ oṣere tiata ni Moji Afolayan, Lola Idijẹ, Ẹ wo ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa gbajúgbajà òṣèré tíátà Yoruba Tóyìn Afọlayan atawọn mii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri

Kunle Afolayan fẹ iyawo rẹ ti a mọ si Tolu ti wọn si bi ọmọ mẹrin.

Kunle Afolayan ṣlaaye fun BBC Yoruba pe oun ko ni ẹsin kankan ṣugbọn oun gbagbọ ninu iwa ọmọluwabi.

Oko ayọkẹle ara ọtọ ti wọn n pe ni Thunder bird 1965 lo fi n ṣe ẹsẹ rin ni titi.

October 1 jẹ ọkan lara awọn sinima Afolayan ti gbogbo aye tẹwọ gba.

Image copyright facebook page
Àkọlé àwòrán Ojopagogo ati Kunle Afolayan

Ta ni Razak Olayiwola, Ojo pagogo?

A bi Rasak Olayiwola ni ọgbọn ọjọ, oṣu kẹsan an ọdun ni ilu Isẹyin nipinlẹ Oyo ni iwọ oorun guusu Naijiria.

Razaq Olayiwola Olasunkanmi ti gbogbo eniyan mọ si Ojopagogo, ti o jẹ odu ri kii ṣe aimọ oloko lagbo tiata ni ilẹ Yoruba.

Orukọ iya rẹ n jẹ Munirat Omowanwa Abẹkẹ sugbọn ti o ti di oloogbe bayi.

Oṣere yii lọ ile iwe Alakọbẹrẹ A.U.D Ebedi, Isẹyin. ati ile iwe girama ti Anwar-U Islam High School, Iseyin ati Ile iwe gbogboniṣe ti ipinlẹ Oyo ni ilu Ibadan

Ni ile iwe yii ni o ti kẹkọọ ijinlẹ gboye nipa orin kikọ.

Ojopagogo fidiẹ mulẹ pe oun ti n ṣe ere tiata ṣaaju ki oun to bẹrẹ ile iwe lilọ ni Ibadan.

O bẹrẹ ere tiata ni ọdun 1983 nigba ti aṣeyẹ kan waye ni Maulud ti eni ti o jẹ ọrẹ ẹgbọn rẹ, Jẹlili Raji fi si inu ere nigba naa.

Ọrẹ ẹgbọn rẹ yii ni Fakewu Baale Larinka to pe e si ere ti a mọ si Egbinrin Ọtẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood:Ṣàgbẹ̀lójú yòyò ni ọ̀ps àwọn òṣèré- Ojopagogo

Ojo pagogo ti ni to ere mejidinlogun ti o ti ti ọwọ rẹ jade lati bii ọdun 1997 si ọdun 2013.

Moji Afolayan ni Olayiwola Razak gbe sile gẹgẹ bi iyawo.

Razak Olayiwola fi ilu Ibadan ṣe ibujoko si.

Ere ori itage Ola Abata ti wọn ṣe lọdun 1986 lo sọ Razak Olayiwola ni oruko tuntun: Ojo pa agogo.

Awọn ẹgbẹ oṣere Labakẹ Theatre group lo ṣe ere naa ni eyi ti alaafin Ikubaba yeye naa wa wo nigba naa.

Ojopagogo tun maa n kọrin yatọ si ere itage ṣiṣẹ.

Loṣu kẹta, ọdun 2015 lo gbe awo orin Isẹyin ati Olaniyonu jade yatọ si kikọ orin ninu awo sinima.

Oni ni ayẹyẹ ajọdun orikadun awọn agba ọjẹ oṣere mejeeji yii: Razak Olayiwola ati Kunle Afolayan.