Premier league: VAR gba ẹ̀tọ́ Aubameyan fún un ní Old Trafford, ọ̀mì ni Manchester United, Arsenal ta

Manchester United ati Arsenal takangbọn Image copyright Getty Images

Agbababọọlu Manchester united, Scott McTominay lo kọkọ gba goolu wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju karundinlaadọta 45'ki wọn to lọ iṣinmi aarin ifẹsẹwọnsẹ naa. Ariwo ayọ nla lo sọ lẹnu awọn ololufẹ Manchester United.

Ko pẹ ti wọn wọle fun abala keji ni Arsenal da ẹyọ kan naa pada nigba ti Bukayọ Saka gba bọọlu fun Aubameyang lati gba sinu awọn ni ariwo ba ta tun sọ geee.

Lati ọpọ ọdun sẹyin ni ija orogun ti wa laarin Manchester United ati Arsenal; tobẹẹ gẹẹ to fi jẹ wi pe nigba kugba ti awọn ẹgbẹ agbabọọẹu mejeeji yii ba ti koju ara wọn ni lala maa n lu.

Itakangbọn laarin olukọni ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji tẹẹẹ, iyẹn Alex Ferguson ati Arsene Wenger tun mu ki ifẹsẹwọnsẹ laarin awọn mejeeji yii o maa legba kan jọrin lọ.

Ifẹsẹwọnsẹ to waye laarin Manchester United ati Arsenal yii ni igba...ti awọn mejeeji yii yoo ma koju ara wọn ni idje Premier League.

ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ yii, ipo kẹrinla ni Manchester United wa lori atẹ igbelewọn Premier league.

Image copyright Getty Images

Ipo kẹjs si ni Arsenal wa lori atẹ naa.

ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ yii, ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo ni manchester United ṣi bori ninu mẹfa ti wọn ti gba ṣaaju ni saa yii.

Bakan naa ni Arsenal ko tii bori ifẹsẹwọnsẹ kankan ni papa iṣire Old Trafford to jẹ ibuba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United.

Image copyright Getty Images

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ naa, olukọni ikọ Arsenal, Unai Emery ni erongba ti awọn gbe wa si Old Trafford ni lati bori. O ni awọn si ti gbaradi niwaju ati ni ẹyin lati mu erongba yii wa si imuṣẹ.

Gbajugbaja agbabọọlu Manchester United ni, Paul Pogba ati marcus Rashford bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa lẹyin ti wọn gbọnra nu kuro ninu bi wọn ṣe fara ṣeṣe.

Awọn ikọ mejeeji lo jẹwọ ọmọọkọ ni ibẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa.