Social Media Slay: Onílé kan bínú fi àwòrán iyàrá ayálágbé ré hàn lórí ayélujéra

Ibusun Arewa kan Image copyright @The Paper
Àkọlé àwòrán Awọn ololufẹ Weibo lanu silẹ lori bi iyara Lisa Li ṣe ri bii...

Yoruba bọ wọn ni afẹfẹ fẹ, a ri furọ adiyẹ ohun lo difa fun arẹwa Lisa Li, to jẹ obinrin kan pataki lori ayelujara lorilẹ ede China sugbọn to jẹ ọbun.

Iya onile rẹ, Madam Chen lo ṣafihan aworan bi iyara ogbontarigi sọrọsọrọ lori ayelujara naa.

O ke gbajare pe ki awọn obinrin maa daa ninu ile naa bi wọn ṣe n daa lorii ẹrọ ayelujara.

Opo eeyan lo ti n pin fidio ti iya onile Lisa Li fi sita lati ṣafihan iwa ọbun rẹ lori ayelujara pe ki awọn ọdọ iwoyi yee ṣoge lasan ṣugbọn ki wọn fi imọtoto kun iwa wọn.

Lisa Li jẹ ọkan lara awọn to ni ẹka iroyin blog ti ara rẹ lori ayelujara to dẹ ni awọn to le ni

Idakeji bi o ṣẹ n ṣe loju opo ẹrọ ayelujara ni arẹwa ọmọ obinrin naa gẹgẹ bi fidio ti iya onile rẹ fihan sita ṣe ri.

Image copyright @Pear video
Àkọlé àwòrán Iya Onile Lisa Li lo gbe fidio to ṣafihan igbe aye ọbun ti Gbajugbaja Lisa Li n gbe hande ni China

Koda, aworan naa ṣafihan igbe ẹran ọsin rẹ ninu iyara rẹ laisọ awọn ohun ẹgbin miran.

O le ni miliọnu eniyan ti wọn ti fesi si ọrọ naa lati igba ti aṣiri rẹ tu pe ọbun paraku ni lati ọwọ iya onile rẹ, Madam Chen,

Oju opo arẹwa Lisa kun fun awọn aworan to rẹwa to le mu ki ẹlomii firu rẹ tọrọ pe ọjọ wo loun naa a ni owo to to bayii.

Opo aworan rẹ lo ṣafihan Lisa lasiko to n rirnrin ajo kaakiri agbaye, nibi to ti n jẹun ni awọn ile olounjẹ to lorukọ lagbaye ati ni awọn ibi inawo eeyan jankan jankan ni awujọ.

Image copyright @Pear video
Àkọlé àwòrán Ileegbe Arewa kan

Iya onile Lisa ni oun mọọmọ gbe fidio naa sita ni ki Lisa le yipada lẹyin ọpọlọpọ igba ti oun ti kilọ iwa ibajẹ yii fun un ni kọrọ ati ni gbangba.

O ni oun fẹ ki Lisa kọ ẹkọ imọtoto ki awọn ololufẹ rẹ to le ni miliọnu kan lori Instagram naa le mọ pe iyatọ wa ninu igbe aye ori Instagram ati igbe aye ẹni loju aye.

Koda, Iya Onile naa ni oun ti fi ọrọ Lisa to ọlọpaa leti tẹlẹ nitori ko tun tete san awọn owo ina tai awọn to n tun ile ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIntersextuality: Dokita ni ká mu èyì tó wù wá nínú jíjẹ́ akọ tàbí abo

Yara naa dọti de ibi pe awọn agbalẹ kọ ti wọn si fariga lati toju yara naa.

Kini Lisa ṣe lẹyin to ri fidio to tu aṣiri rẹ yii?

Ṣugbọn lati igba ti ọrọ naa ti wa lori ẹrọ ayelujara ni ọmọbinrin naa ti n bẹbẹ lati yi pada.

Lisa Li jẹ olokiki ni orilẹ ede China lori ẹrọ ayelujara bii iṣana ẹlẹta, ti aworan rẹ si rẹwa lọpọlọpọ.

Image copyright @Pearl video
Àkọlé àwòrán Lisa trọ aforijin lọwọ iya Onile rẹ lẹyin ti fidio lu jade tan

Ṣugbọn lati igba ti akara rẹ ti tu sepo lo ti yipada ti o si ti fihan gbogbo eniyan ni ojule ti o wa ni ariwa Xi'an ti o si ti di ilumọọka.

Nigba ti o to asiko kan, o tọrọ aforiji lọwọ iya onile rẹ ti o ṣalaye pe iṣẹ lo faa ti iru iṣẹlẹ bẹẹ ṣe waye pe atunṣe yoo wa.

Pupọ lara awọn ololufẹ rẹ lori ẹrọ ayelujara ti ko din nim ọgọta ẹgbẹrun lo kọ iwe ranṣẹ si lati dẹyin lẹyin rẹ ṣaaju akoko ti o fi tọrọ aforiji naa.

Eyi kii ṣe igba akọkọ ni ilẹ China ti iru rẹ yoo waye, iru rẹ waye ni Osu keje nipa ọmọ obinrin kan laimọ pe arugbo ni.

Lisa ṣalaye fun onile rẹ pe oun ti gbọ ẹkọ ti o fẹ kọ oun nitori oun ko mọ pe ile oun dọti to bẹẹ ati pe iṣẹ lo gbomi mu fun oun ti oun ko si ri aaye tun ile ṣe.

Ninu atẹjade kan ti Lisa fun ile iṣẹ iwe iroyin: The Paper lo ti tọrọ aforijin to ṣalaye pe ọpọ atẹjiṣẹ ni oun ti ri gba lati ọdọ awọn ololufẹ rẹ.

Lisa gbe igbesẹ lati tun iyara rẹ ṣe!

Image copyright @pear video
Àkọlé àwòrán Lisa bẹrẹ atunṣe si iyara rẹ lẹyin o rẹyin

Ni kete ti Lisa pada sile lẹyin ti ọpọlọpọ miliọnu eeyan ti sọrọ lori ayelujara ni Lisa Li ti bẹrẹ si ni tun iyara rẹ ṣe.

Kini awọn ololufẹ Lisa ṣe lori ayelujara?

Ọpọ awọn ololufẹ Lisa lori ayelujara ni wọn kọkọ fi ṣe yẹyẹ nigba ti fidio kan jade to ṣafihan Lisa to n ko igbẹ aja rẹ ninu iyara rẹ.

Igbesẹ ayipada rẹ yii pada ya pupọ ninu awọn ololufẹ rẹ lẹnu ti awọn miran bẹrẹ si ni kan saara si Lisa.

Fidio naa ni imọran to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọta laarin wakati melo to fi sita.

Awọn miran si ni awọn ko ni tẹle e mọ nitori pe o n gbe igbe aye féèkì ti ko ki n ṣe ootọ.

Image copyright The paper
Àkọlé àwòrán Fidio naa ni imọran to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọta laarin wakati melo to fi sita.

Awọn miran ni igbesẹ to fi yọ kuro ninu awọn nkan to ti gbe sori ayelujara tẹlẹ naa ku diẹ kaato.

Awọn ololufẹ Lisa mii ni ko ni ootọ ati pe o ti ṣi awọn ọdọ miran lẹsẹ pe igbe aye ori ayelujara lo dara.

Kii ṣe igba akọkọ ti iru nkan bayii maa ṣẹlẹ ni orilẹ-ede China ni yii.