Visa free: Àwọn Orílẹ-èdè tí wọn fún ọmọ Nàìjíríá lánfàní ìwé igbeluu ọ̀fẹ́

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Oko Ofurufu ṣetan lati gbe ẹnikẹni to ba fẹ rinrinajo lọ si awọn orilẹ-ede wọnyii.

Eto irin ajo lọ silẹ okeere awọn ọmọ Naijiria lo nilo igbaradi to muna doko latari ipo ti paali irinajo naa wa.

Bakan naa ni iwe aṣe igbelu tabi iwe aṣẹ wiwọ ilu tabi orilẹ-ede kọọkan [visa] jẹ ohun ti o gba oogun lọpọlọpọ lati ri gba fun irin ajo naa.

Sibẹ awọn orilẹ-ede kan ni ilẹ Adulawọ wa to n fi aaye gba irinajo si ọdọ wọn lai gba iwe aṣẹ igbelu tabi iwe iwọle niwọn igba ti paali irinajo to pe ye ba ti wa.

Wo awọn orilẹ-ede ti a fẹ darukọ yii fi aaye gba wiwọ ilẹ wọn lai si idaamu tabi dandan iwe aṣẹ. Ṣugbọn awọn kan beere fun iwe irinna naa lẹnu ọna ibode atiwọle si orilẹ-ede wọn.

1. Rwanda:

Orilẹ ede yii jẹ eyi ti o ni imọ toto julọ ti ọpọ awọn oludokowo ati awọn arinrin ajo afẹ si fi ṣe ibi ojukkọ ogun ni ọdun 1994,ni iyatọ ti wa.

O tun jẹ orilẹ ede ti ko ni idojukọ eto abo ti iwa ọdaran ko si ṣe bẹẹ wọpọ.

2. Djibouti:

Ni Iwọ Oorun ilẹ Afirika, ọkan pataki ibi ti o yẹ lati bẹwo lati orilẹ-ede Naijiria ni Ilu yii.

O ṣeeṣe ki o gba iwe aṣẹ igbelu ṣugbọn pẹlu owo ti ko ga ju ara lọ, ṣugbọn ti ilẹ naa ni awọn ibi abẹwo to lọọrin.

Awọon ibi abẹwo yii ni Odo Assal, ti o jẹ eyi ti o kere si ori ilẹ julọ ni ilẹ Adulawọ ti o si jẹ ikẹta iru rẹ ni agbaye lẹyin odo Galilee ati Okun pupa.

3. Morocco:

Aṣa, Oju Ọjọ ati awọn ohun amuyẹ ilu yii jẹ ko jẹ ibi aayo fun awọn ololufẹ.

Awọn ara meeriri ile ounjẹ, ibusọ, ati ibi igbafẹ kaakakiri le mu ki ololufẹ gbogbo gbagbe ile ile.

4. Cape Verde:

Orilẹ ede yii jẹ ibi omi ti o wa ni ila Oorun Adulawọ. O tun jẹ ọkan pataki lara awọn ibi igbafẹ julọ ni ilẹ Adulawọ.

Oju ọjọ ilẹ naa dara ti ayika orilẹ ede naa si rẹwa.

5. Kenya:

Ilu yii ni oriko awọn eranko nla nla, Safari ati awọn ibi itan. Awọn ilu bii Nairobi ati Monbassa jẹ ibi ti o dara.

Enu ọna ilu naa ni eniyan ti le gba iwe irinna bakan naa.

6. Uganda:

Ila Oorun Aduilawọ ni ilu yii ti o si ni ibi itan bii obo Victoria ati awọn miiran ti o si fi aaye gba gbigba iwe ni ẹnu ọna iwọle.

7. Sudan:

Ilu yii jẹ ibi ti o ni agbegbe awọn eranko ti o si ni ojuko ibi igbafẹ ṣugbọn ti iwe irinna gbigba rẹ jẹ lati ẹnu ọna abawọle.

Awọn Orilẹ ede miran ti ko nilo iwe aṣẹ igbelu fun awọn ọmọ Nigeria ni ;

8. Barbados:

Orilẹ ede yii wa ni Ila Oorun ilẹ Afrika ti o si jẹ bii ọgọrun kilomita si Iwọ Oorun Odo Caribbean ati Odo Windward.

Abẹwo ọmọ Naijiria si ilu yii yoo fun ẹni naa ni anfaani lati lo oṣu mẹfa lai gba iwe aṣẹ.

O jẹ ilu ti o ni ibi igbafẹ ẹgbẹ omi julọ ati ẹja odo.

9. Bangladesh:

Orilẹ ede yii jẹ ọkan lara orilẹ ede ti o pọju lọ lagbaye.

Bakan naa ni o maa n fun awọn ọmọ Naijiria ni anfani ọgbọn ọjọ ki wọn to gba iwe aṣẹ igbelu.

Bakan naa ni iru ẹni bẹẹ yoo ṣafihan ẹẹdẹgbẹta owo dọla tikẹẹti ipada sile.

Igbadun rẹpẹtẹ n bẹ ni Ilu Port ni Cittagong fun faaji ti ko lopin.

10. BURKINA FASO:

Ofẹ ni iwe igbelu orilẹ ede yii ti o wa ni Iwọ Oorun Alawọ dudu.

Orilẹ ede yii ni o ṣe igbalejo iṣafihan aṣa ati ohun iṣẹnbaye, Ouagadougou ti o si gba ami ẹyẹ julọ ni ilẹ adulawọ.

Burkina Faso jẹ orilẹ ede ti awọn ọmọ Naijiria fẹran lati maa lọ ti o si ni Wura ati Fadaka lọpọ yanturu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....

11. BENIN REPUBLIC:

Osu Mẹta pere ni wọn fun awọn ọmọ Naijiria lati gbe ni ilu naa lai si iwe aṣẹ igbelu .

Orilẹ ede naa sun mọ Naijiria daada ti o si ni ọpọlọpọ ojuko igbafẹ bii ibi afọwọsi ajọ UNESCO ti a mọ si Pendjari Park.

12: BURUNDI:

O wa ni ila Oorun Adulawọ ti o si fun ọmọ Naijiria ni anfani ọgbọn ọjọ lati gbelu laisi iwe aṣẹ.

Ilu naa ni a mọ si orilẹ ede ti o mọ nipa iṣẹ ọwọ bii apẹrẹ hihun,ṣiṣe ere ati amọ mimọ.

Ọkan pataki lara ohun ti wón tun mọ ni ilu lilu. Awọn alulu fọba ti orilẹ ede naa ti wa lẹnu rẹ bayii bii Ogoji Ọdun.

Sisọ itan, alọ apagbe ati Ijala jẹ ohun amuyẹ orilẹ ede naa.

13: CHAD:

Ilu yii wa ni Ila Oorun Adulawọ ti o n fun ọmọ Naijiria ni anfaani iwe aṣẹ igbelu. Ṣaa ti ṣafihan ẹri pe kii ṣe pe lailai ni iru ẹni bẹe fẹ maa gbe ilẹ naa.

Ti gbongan ibi iko ohun Iṣẹn baye si naa ko gbẹyin.

14. CAMEROON:

Oṣu mẹta ni orilẹ ede yii naa fun gbigbelu awọn ọmọ Naijiria lai gba iwe Aṣẹ igbelu orilẹ ede naa. Aginju nla ti awọn ẹrenko ngbe pọ ni ilu naa.

Bakan naa ni gbongan ibi iko nkan iṣẹnbaye si wa ni Yaounde ati Mvog-Betsi ti o jẹ ibi ti ẹranko n la wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀èdè Nàìjíríà sọ èrò wọn lórí Nàìjíríà

15. COTE D'IVOIRE:

Orilẹ ede yii la n pe ni Ivory Coast tẹlẹ ti o ni ọpọ ohun alumọni ti yoo mu dide larinnrin.

Ibi igbafẹ ti Assinie , Parc National de Tai, Ori Oke Artsy jẹ ọkan lara awọn ibi igbafẹ.

O tun le jẹ igbadun ririn ajo ori omi tabi ibi itaja ti o wa ni Treichville tabi Cocody.

16. COMOROS:

O le rin irin ajo lọ si orilẹ ede yii lai gba iwe aṣẹ irinna ṣugbọn ti o le ri iwe naa gba ni aadọta dọla.

Orilẹ ede yii ni igun ibi omi mẹrin ti o si ti ni idagbasoke pẹlu yẹpẹ funfun.

Awọn adan nla ,okuta ati igbo ti o pọ jantii rẹrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBlacksmith: èmí ni ìran keje tó jogún iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ yii- Alatiṣe

16 CAPE VERDE:

O wa ni Iwọ Oorun Afrika ti o si ni anfaani Oṣu kan lati fun ọmọ Naijiria.

Awọn alaṣẹ ilẹ naa yoo gba ẹri pe kii ṣe wi pe lati gbe ni ile naa patapata ṣugbọn fun igba diẹ.

17. CAMBODIA:

O gbọdọ fi iwe aṣẹ igbelu rẹ han ni kete ti o ba ti n balẹ si ilu naa lẹyin ọgbọn ọjọ.

Orilẹ ede naa ni a mọ si eyi ti o ni ojuko ibi omi ti o dara fun igbafẹ ati pẹpẹ atijọ.

O le debẹ ni oṣu kejila nigba ti wọn ba n ṣe Ajọdun Omi.

18. DOMINICA:

Ookanlelogun ọjọ pere ni anfani mọ ni ilu yii.

19. DJIBOUTI:

Ila Oorun Afrika ni ilu yii wa ti o si bere fun aṣẹ iwe igbelu.

20. FIJI

Guusu Ibi Omi Pacific Afrika ni ilu yii naa wa. Oṣu mẹrin ni anfaani iwe aṣẹ igbelu.

Ati awọn orilẹ-ede ti wọn ni awọn ofin isalẹ wọnyii:

GHANA - Iwọ Oorun Afrika ni ilu yii wa. Ko si dandan aṣa iwe igbelu.

GUINEA - Iwọ Oorun Afrika ni ilu yii wa ti ko nilo aṣẹ iwe igbelu,

GUINEA BISSAU - Oṣu mẹta pere ni aigbawe aṣẹ ilu yii ti o si wa ni Iwọ Oorun Afrika.

GAMBIA - Oṣu mẹta pere naa ni ohun ti o si wa ni Iwọ Oorun Afrika bakan naa.

HAITI - Agbegbe Caribbean ni ilu yii wa. Oṣu mẹta naa ni anfani iwe igbelu na.

IRAN -Aarin gbungbun Ila Oorun Afrika ni o wa.

Bakan naa ni o le ṣabẹwo si awọn orilẹ-ede wọnyii lai nilo iwe aṣẹ Igbelu.

Samoa: aṣẹ iwe igbelu fun osu meji

Senegal: Ọfẹ ni

Seychelles: Iwe aṣẹ fun ọgbọn ọjọ

Somalia: Gbigba aṣẹ iwe igbelu

Sri Lanka

Tanzania: de pelu iwe aṣẹ igbelu

Timor - Leste: Iwe aṣe igbelu fun ọgbọn ọjọ

Togo: laisi iwe aṣe igbelu

Tuvalu: de pelu iwe aṣẹ lẹyin oṣu kan.

Uganda: de pẹlu iwe aṣẹ igbelu

Vanuatu: de pelu iwe aṣẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri