Lizzy Anjorin vs Toyin Abraham: Ẹ wòó ẹ fi wọ́n sílẹ̀, ìgbà ọtun ń bọ láipẹ́ -Toyin

Toyin Abraham Image copyright Instagram/Toyin Abraham

Gbajugbaja Oṣere tiata Toyin Abraham ti gbogbo aye mọ si Toyin Aimakhu tẹlẹ ni o ti ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ lori ẹrọ ayelujara.

Toyin Ajeyemi foju hande fun igba akọkọ lati sọrọ lati igba ti aawọ ti suyọ laarin ohun ati akẹgbẹ rẹ, Lizzy Anjọrin.

Toyin dupe lọpọlọpọ lọwọ gbogbo awọn ololufe rẹ fun atilẹyin ati ifẹ ti wọn ni si i lati ẹyin wa.

Ninu ọrọ rẹ , o dupẹ fun aduroti ati amọran ti o n ri gba lọwọ onipo jipo awọn onibara rẹ.

O wa parọwa si gbogbo awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn ma ṣe sọrọ alufanṣa pada si ẹnikẹni to ba sọ iru ọrọ bẹẹ.

Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Toyin Abraham

O ni to ba wa ni ẹnikẹni tabi eeyan keeyan to ba n binu tabi fapa jana, ki wọn o fi silẹ pe ki iru ẹni bẹẹ lee ri ogo Oluwa ninu aye ohun.

Bakan naa lo ṣe lalaye pe, oun ati gbogbo alatilẹyin oun pata kii ṣe onijagidi jagan, ti wọn si kawe bẹẹ naa ni wọn ni ọpọlọ.

Lo ba ni keṣekeṣe ni wọn ri o, pe kasakasa nbọ lọna, eyi to jẹ baba keṣekeṣe ni daada.

Ni akotan , ko ṣai dupe pupọ lọwọ awọn ti o jẹ olubadamọnran rẹ.