"Kí ló ṣe jẹ́ pé èmi ni yóò ní àrùn jẹjẹrẹ lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlá?"
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ovarian Cancer: Kelliyah Ashley ní ṣe ní ikùn òun le gbandi bíi olóyún

Ọlọrun ma fi aisan se wa, boya yoo gbọ oogun tabi ko ni gbọ ni adura ti ọpọ eeyan maa n gba.

Sugbọn ki ni ka ti sọ ti ọmọ ọdun mẹrinla, Ashley Kelliyah, to se agbako aisan jẹjẹrẹ apo ẹyin ile ọmọ, lai jẹ pe o ti bimọ ri, fun ọmọ lọmu tabi lo oogun lati dena oyun ri.

Nigba to n salaye ohun ti oju rẹ ri fun BBC, lasiko ti aisan jẹjẹrẹ apo ẹyin ile ọmọ naa n baa finra, Kelliyah ni irora ti oun la kọja lagbara pupọ, oun ko lee sun, ti oun si maa n sọkun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iya Kelliyah fikun pe, jẹjẹrẹ ti iwọn rẹ to kilo marun, to si gun de oke aya Kelliyah ni awọn dokita fi isẹ abẹ gbe jade ni ikun ọmọ oun.

Amọ Dokita Adeọla Ọlaitan ti wa salaye pe, irufẹ aisan jẹjẹrẹ yii kii saba wọpọ laarin awọn ọdọ ti ko tii loyun ri, bi o tilẹ jẹ pe ko si obinrin ti ko lee mu.

Ẹ wo fidio yii lati mọ ohun ti ọdọlangba naa la kọja lọwọ aisan jẹjẹrẹ.