Bobrisky: Ìjọba ní kí àwọn ọmọ Naijiria yàgò fún Bobrisky

Idris Okuneye, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky Image copyright @bobrisky222

Ijọba apapọ ti kilọ fun awọn awakọ lati ma a sọra fun Bobrisky paapaa nipa ajọlo yara igbọnsẹ.

Ijọba apapọ ni awọn fi ikilọ yii lede lẹyin ti Bobrisky da rogbodiyan kan silẹ ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ni ilu Abuja, nigba ti wọn ri i to n lo yara igbọnse awọn obinrin.

Ijọba wa rọ ẹka ilera lorilẹede Naijiria lati la awọn eniyan lọyẹ nipa ewu to wa ninu lilo yara igbọnse kan naa pẹlu Bobrisky.

Ijọba fi kun wi pe, oun to lewu pupo ni fun obinrin lati ma a ba Bobrisky lo ile igbọnsẹ pọ, wọn ni o buru ju aisan Ebola lọ.