Àṣírí tú! Olùkọ́ fásitì méjì ń bèèrè ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ fún máákì
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

Yoruba ni ẹsin kii jẹ koriko abẹ rẹ amọ eyi ko ri bẹẹ fun awọn olukọ fasiti meji kan to n beere fun ibalopọ lọwọ akẹkọ.

Fọnran aworan yii, lo je ifinmu finlẹ ikọ ọfintoto BBC Africa Eye ni fasiti meji lẹkun iwọ oorun Afirika, eyiun fasiti Eko taa mọ si UNILAG ati fasiti Ghana.

Fọnran yii si lo n se afihan awọn olukọ fasiti meji lawọn ileẹkọ mejeeji yii ti wọn n beere ibalopọ lọwọ awọn akẹkọ to fẹ wọle sọgba ile ẹkọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Koda, awọn akẹkọjade kan lawọn ileẹks naa tun salaye ohun ti oju wọn ati ti awọn akẹẹgbẹ wọn kan ti ri lọwọ awọn olukọ to kundun ibalopọ naa.

Ẹ wa nkan fidi le lati wo ẹkunrẹrẹ fidio naa, amọ o seese ki ara ta yin gẹgẹ bii abiamọ abi akẹkọ.