Lamido Sanusi: Èèyàn tó pọ̀ ní Nàìjíríà kìí ṣe dúkìá, gbèsè ni

Ilu Eko Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Muhammadu Sanusi: Èèyàn tó pọ̀ ní Nàìjíríà kìí ṣe dúkìá, gbèsè ni

Emir ilu Kano, Mohammadu Lamido Sanusi (II) sọ oko ọrọ kan niluu Abuja lọjọ Aje nibi to ti sọ pe gbese ni iye eeyan to wa lorilẹ-ede Naijiria bayii jẹ.

O ni nitori pe Naijiria ni ero to pọ ti awọn eniyan pọ pupọ ko sọ pe o ja si èrè fun wa.

Sanusi sọrọ yii nibi apero lori ọrọ aje ẹlẹẹkẹẹdọgbọn iru rẹ to n lọ lọwọ niluu Abuja.

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayode Fayemi ati oludasilẹ ṣọọṣi Kukah Centre, Bisọbu Matthew Kukah naa wa lara awọn to peju sibi apero ọhun.

Emir Kano ṣalaye pe lootọ ni pe Naijiria le ṣe ohun to pọ nitori iye eeyan to wa nibẹ ṣugbọn ko ri bẹẹ lasiko yii, pipọ t'eeyan pọ ni Naijiria ko tii maa mu anfaani kankan ba orilẹ-ede naa bayii.

Sanusi ni ko tii si eto ti yoo jẹ kawọn ẹgbẹlẹgbẹ ọdọ wulo fun orilẹ-ede Naijiria lọjọ iwaju.

Image copyright Alamy Stock Photo
Àkọlé àwòrán Sanusi sọrọ yii nibi apero lori ọrọ aje ẹlẹẹkẹẹdọgbọn iru rẹ to n lọ lọwọ niluu Abuja.

Emir Sanusi ni iṣẹlẹ ijinigbe, idigunjale, igbesunmọmi, ikọlu laarin agbẹ ati darandaran n waye nitori bi awọn eeyan naa ṣe n pọ si ni Naijiria.

O fikun ọrọ rẹ pe bi eeyan ṣe pọ to ni Naijiria ko tii ṣe orilẹ-ede naa loore gẹgẹ bi ọpọ ṣe ro.

Sanusi ni Naijiria ko tii dagba gẹgẹ bi orilẹ-ede de ibi ti awọn eeyan to wa nibẹ yoo jẹ dukiẹ fun un.

Sanusi gbamọran pe ki awọneniyan Naijiria naa maa ṣamulo ọpọlọ wọn si iwa daadaa ati aṣeyọri ninu imọ bii sayẹnsi lasiko yii.

Nibayii, awọn eeyan to wa ni Naijiria din mẹwaa ni igba miliọnu eeyan bayii.