2020 Budget: Àwọn gbèsè Nàìjíríà rèé

Aba Eto isuna Naijiria

Bi a ba wo agbekalẹ iṣiro bi idagbasoke eto isuna lorilẹede Naijiria ati iye gbese to ti wa nilẹ, o ṣeeṣe ka mọ ibi ti Naijiria n mori lọ.

Lọjọ diẹ sẹyin ni aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣe agbekalẹ aba isuna ọdun 2020.

Nibi ayẹyẹ kan to waye loni nile aṣofin ilẹ Naijiria, Buhari sọ pe oun to jẹ ijọba logun ni pipari awọn akanṣe iṣẹ to ti wa nilẹ.

O ni bi kii ba ṣe awọn iṣẹ pataki ti ko ba pari lati ọdun 2019 tawọn fi aye kalẹ fun, awọn ko ni dawọ le iṣẹ tuntun kankan bi kii ṣe ki ijọba pari eleyi to ti wa nilẹ.

Buhari ṣalaye pe ẹka ijọba to ba kọ lati pa to gbedeke iye owo ti awọn fun wọn wọle, yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Ṣaaju ki aarẹ to kan si ile igbimọ ni o ti dari ipade pataki igbimọ alaṣẹ orileede Naijiria(FEC).

Origun pataki ni agbekalẹ aba isuna yii jẹ ninu eto iṣejọba. Lẹyin tawọn ọmọ ile aṣofin ba ti gba aba yii ti wọn si mu awọn atunṣe diẹ wa, aarẹ yoo buwọ lu aba ọhun ti yoo si di ofin ṣiṣe akoso nina owo fọdun 2020.

Image copyright NTA

Bakanna ni aarẹ sọ pe awọn ileeṣẹ ijọba ko gbodọ gba awọn eeyan tuntun siṣẹ bi ko ba si iyọnda lati ọdọ ijọba.

O tẹsiwaju lati ṣe atupalẹ iye owo ti awọn ẹka kankan yoo ri gba ni owo ina fawọn akanṣe iṣẹ.

Diẹ ninu awọn to ka kalẹ ree:

  • Iṣẹ ode ati ile'gbe-262 biliọnu
  • Ẹka Oun amuṣagbara-127 biliọnu
  • Ẹka irina- 123 biliọnu
  • Ẹkọ alakọbẹrẹ- 112 biliọnu
  • Aabo-100 biliọnu
  • Ẹka eto ẹkọ- 48 biliọnu
  • Ẹka eto ilera - 46 biliọnu
  • Ẹka eto ọgbin- 83 biliọnu
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAfrica Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́

Oun táa ti jábọ̀tẹ́lẹ̀ ṣáájú ọ̀rọ̀ ààrẹ Buhari

Gbogbo ètò lo ti tò nílé ìgbìmọ̀ asofin àgbà l'Abuja ni ìmúrasilẹ fún kíka abá ìsúna fún ọdún 2020, eyi ti aarẹ Muhammadu Buhari yoo se lonii ọjọ Isẹgun.

Gẹ́gẹ́ bi ìròyiìn ṣe sọ, apá ibikan ni ilé igbimọ asofin lo ti gba àwọ tuntun, tí ètò ààbò ni àyika gbogbo ile ìgbìmọ̀ náà si ti wà ni ṣẹpẹ́ fún ètò naa, ti yóò bẹ̀rẹ̀ ni ààgo meji ọ̀sàn òní.

Koda, a gbọ pe àrà ọ̀tọ̀ ni ètò ayẹwo iforúkọ sílẹ fàwọn akọ̀ròyìn, àwọn ọlọ́pàá àti àwọn oṣìṣẹ́ ti yóò wà níbi àyẹyẹ náà.

Gbogbo ile itaja àti ilé ifowopamọ to wà nínú ọgba náà pẹ̀lú tí gbe kọ́kọ́rọ́ le ìlẹ̀kùn wọ́n.

Bakan naa, gbogbo òṣìṣẹ́ ilé aṣofin ti kò ba ni ǹkan ṣe pẹlú ètò ìsùná ko ni wọlé rárá sínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin rárá lásìko ti ààrẹ bá ń ka ètò ìsúná.

Image copyright @MBuhari

Sugbọn ohun to wa n kọ ọpọ eeyan lominu bayii ni pe, àwọn alákoso ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kò tíì rí ojúùtú sí gbogbo àwọn ẹ̀rọ tó wà lẹ́nu ọ̀nà abawọle ile asofin apapọ to ti dẹnu kọlẹ.

Awọn ẹrọ naa ni wọ́n fi ń ṣe àyẹwọ ẹni ti ó ba gbé ǹkan to le panilára dáni, pàápàá jùlọ, èyí to wà ni ẹnú ọ̀nà àbáwolé ibi tí ètò náà yóò ti wáyé, to ti dẹnu kọlẹ.

Ibeere to si n gba ọkan ọpọ eeyan ni pe se aabo wa fun aarẹ Buhari lonii bi, bo se n gbe aba eto isuna kalẹ.