Fídíò rèé nípa bí Aláké tuntun ṣe ń gba ìwúre lábẹ́ Olúmọ kó tó gba adé
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olumo Rock: Òrìṣà Igùn lọba ọ̀pọ̀ òrìṣà tó wà lábẹ́ Olúmọ tó ń dáhùn àdúrà

Ẹnikẹni to ba lọ silu Ẹgba, eyiun Abẹokuta, ti ko si de ori oke Olumọ, a jẹ pe abẹwo rẹ ko tii pe.

Eyi lo n sọ bi Oke Olumọ ti se pataki to fun awọn Ẹgba nitori abẹ rẹ ni wọn sa si lasiko ogun, ibẹ si ni ilu Abẹokuta ti gberasọ.

Yatọ si pe oke Olumọ jẹ ibudo asa ajogunba ati irinajo afẹ nipinlẹ Ogun, ohun pataki to tun maa n waye lori oke yii ni ọpọ orisati wọn n bọ nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ti ikọ iroyin BBC Yoruba sabẹwo lẹẹkansi si oke Olumọ lati mọ ohun to n waye labẹ apata naa ati ojuse awọn iya agba to wa nibẹ, ẹnu ko gba iroyin.

A gbọ pe ọpọ orisa bii Ọbaluaye, Ọbatala, Ọsun, Sango ati Igùn lo wa labẹ Olumọ ti wọn n bọ sugbọn orisa Igùn ni ọba gbogbo wọn.

Simiatu Gbesa, tii se igbakeji iya olorisa labẹ Olumọ salaye pe ko si ohun tawọn beere lọwọ awọn orisa naa, ti wọn kii fun awọn, koda bi alaisan ba mu omi kan to wa labẹ oke naa, kiamọsa ni ara rẹ yoo ya.

Gbesa fikun pe ọba tuntun ti yoo ba jẹ nilẹ Ẹgba gbọdọ wa se awọn etutu kan loke naa, ki wọn to gbe ade lee lori, to si tun salaye lori awsn igbesẹ ti ọba naa yoo gbe labẹ Olumọ, ko to di ọba.

Ẹkunrẹrẹ fidio naa ree, ẹ woo: