2020 Budget: Owóyàá lábẹ́lé àti nílẹ̀ òkèèrè nìjọba fẹ́ fi gbọ́ bùkátà ìṣúná 2020

Oju ọ̀na to bajẹ Image copyright @Oshofaze

Ni ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹjọ, osu Kẹwa ọdun 2019 ni aarẹ Muhammadu Buhari gbe aba eto isuna ọdun 2020 kalẹ siwaju ile asofin apapọ ilẹ wa.

Apapọ owo to to Triliọnu mẹwa o le diẹ naira (₦10.33trn) ni ijọba apapọ yoo fi gbọ bukata eto isuna ọdun to n bọ naa pẹlu afikun pe, owoya labẹle ati nilẹ okeere si wa lara ọna ti wọn yoo gba ri owo gbọ bukata eto isuna naa.

Nigba to n salaye siwaju lori bi owo yoo se tẹ ijọba apapọ lọwọ, Buhari ni owo ori ọja ti lọ soke sii lati ida marun si meje ati aabọ, ti eto isuna naa si da lori ilana owo ori ọja tuntun naa.

Amọ ko sai yan pe awọn sja kan wa ti wọn ko ni gba owo ori lori wọn, lara awọn ẹka ti eyi si kan ni ẹka kata-kara oogun,eroja eto ẹkọ ati eroja ounjẹ.

Awọn ọja ti ko ni sanwo ori:

 • Buredi alawọ rẹsurẹsu ati funfun
 • Awọn ounjẹ onihoro bii agbado, irẹsi, wiiti, jero ati ọka baba
 • Ẹja, ẹran miliki, fulawa, atawọn ounjẹ to ni sitaaṣi
 • Eroja eso, ewebẹ ati awọn ipanu bii ẹpa
 • Eroya to jẹ gbongbo bii isu, koko, poteto
 • Awọn ohun to n tara ohun ọsin abiyẹ jade bii ẹyin
 • Omi mimu

Ipese oju ọna:

Ko tan sibẹ, ijọba tun ya owo sọtọ lati fi se awọn opopona ati afara mọkandinlogun ni ipinlẹ mọkanla ni Naijiria.

Image copyright OTHERS
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gbé àbá isúná tó lé ní triliọnu mẹwa Naira ka íwájú Ilé ìgbìmọ̀ Asòfin fún ọdún 2020.

Àtúpalẹ̀ àbá ètó ìsúná ọdún 2020 rèé, wo bó ṣe kàn ọ́ sí:

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ wi pe awọn eniyan ko ni ma a san owo ori lori awọn ounjẹ kọọkan lati jẹ ki owo rẹ dinku.

Aarẹ Buhari sọ eyi lasiko to n gbe aba isuna to le ni triliọnu mẹwa (N10.33 trillion) Naira ka Ile Igbimọ Asofin apapọ fun ọdun 2020.

Awọn ounjẹ bii isu, ẹja, miliki, awọn ounjẹ alagbado, ounjẹ ti wọn se pẹlu iyẹfun, eso, ẹfọ, oogun ibilẹ, ẹran ati omi lo bọ lọwọ owo ori naa.

Àtúpalẹ̀ àbá ètó ìsúná ọdún 2020:

 • Aba eto isuna fun isẹ ode ati ilegbe lo gba iye owo to pọ julọ fun aba isuna ọdun 2020 pẹlu biliọnu lọna ọtalerugba o le meji Naira (N262 Billion)
 • Ile isẹ to wa fun eka to n risi ọrọ ina ọba lo tun gba eto isuna to to biliọnu lọna mẹtadinlaadoje naira, N127 billion
 • Eto irinna ọkọ gba biliọnu mẹtalelọgọfa naira (N123 billion), nigba ti ile isẹ to n bojuto ọrọ agbegbe Niger-Delta lo gba aba isuna to kere julọ
 • Ọgbọn biliọnu Naira ni ijọba gbe kalẹ fun awọn eto iranwọ fun awọn eniyan bii N-power ati eto ounjẹ fun awọn akẹẹkọ ni ile iwe
 • Triliọnu meji Naira o le diẹ ni ijọba ya sọtọ fun awọn akanse isẹ ti ijọba fẹ se fun ọdun 2020, eleyii ti Aarẹ sọ wi pe awọn yoo ya sọtọ fun pi pari isẹ akanse ti wọn n se lọwọ
 • Aarẹ Buhari ni erongba ijọba ni wi pe owo ori ti awọn yoo fikun lati ida marun si ida meje abo ni yoo jẹ ki eto isuna ọdun 2020 gberasọ.
 • Bakan naa ni Aarẹ Buhari pasẹ ki wọn gbegile sisan owo osu awọn oṣiṣẹ ti ijọba ko ba ni akọsilẹ orukọ titi di ipari Osu Kẹwa, ọdun 2019 yii