Toxic Cream: Uk ní kí tọkọtaya san £17,000 owo itanran ati ṣíṣe iṣẹ́ ìlú fún ọgọ́ta wákìtí

Awọn ipara ibora Image copyright Others

Bayii laa se nile wa, eewọ ibomiran ni.

Bi o tilẹ jẹ wipe asa tita ọsẹ ati ipara ibora wọpọ lorilẹede Naijiria, ti ko si si ẹni to n moju to ipeniye rẹ, amọ tọkọtaya kan, ti wọn jẹ ọmọ Naijiria ti ri ẹwọn he lori iwa yii nilu London.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jonathan Ikpere ati aya rẹ, Holiness ti wọn n gbe lagbegbe Southsea nilu Ọba, lo maa n ko oniruuru ọsẹ ati ipara ibora to lewu wọle silẹ United Kingdom lati Naijiria, Pakistan ati China.

Image copyright Others

Awọn ọja to n se ijamba fun awọ ara naa si ni wọn maa n polowo rẹ tantan tan lori ayelujara pe ki awọn araalu wa ra, bẹẹ si ni ọpọ eroja ọsẹ ati ipara ibora naa nijọba ti fi ofin de ninu ile wọn.

Image copyright Others

Gẹgẹ bi iroyin naa ti wi, awọn tọkọtaya naa ti ri ti aje se nidi okoowo laabi ọhun, ti wọn si ti ri ẹgbẹlẹgbẹ owo pọun nidi okoowo naa.

Iwadi ijọba ilẹ UK lo mu ki afẹfẹ fẹ si idi tọkọtaya naa, ti akara si tu sepo pe awọn eroja to n bo ara naa, ti wọn n ko wọle lati ilẹ adulawọ naa lo lee ba awọn ara jẹ, ti wọn si ti gbẹsẹ le ọpọ ọja ọhun to to ẹgbẹrun mẹta to wa ninu ile Ikpere.

Image copyright Others

Gbogbo awọn ẹsun yii ti wọn fi kan tọkọ́taya ọhun, ni wọn gba pe awọn jẹbi rẹ, ti ijọba si ni ki wọn lọ san owo itanran to jẹ ẹgbẹrun lọna mẹtadinlogun pọun (£17,000) ati sise isẹ ilu fun ọgọta wakati.