Wo ọ̀nà tí wọn ń gbà dá ẹmu tíí ṣe ìṣẹ́ àbáláyé
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Palmwine Tapping: Ọ̀dọ́mọdé àdẹ́mu ní ìṣẹ́ náà kò wú òun lórí

Lara awọn isẹ abalaye nilẹ Yoruba ni ẹmu dida jẹ, eyi ti awsn eeyan n lo fun ayẹyẹ ki ọti oyinbo to de.

Ọna lati mọ bi wọn se n da ẹmu lo gbe BBC Yoruba lọ silu Ilaramọkin, ta si se alabapade Oluwadamilare Alutundun.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oluwadamilare ni baba oun lo fi isẹ naa le oun lọwọ, ti awọn si maa n pa to ẹgbẹrun mẹta si marun naira ti ọja ba ya.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo salaye igbesẹ ti eeyan gbọdọ gbe, ko to da ẹmu eyi to da lori igboya, to si sekilọ pe ẹnikẹni ti ooyi ba n kọ ko lee da ẹmu.

O ni ẹẹmeji lawọn maa n kọ ọpẹ kan lojumọ amọ isẹ naa ko wu oun lori rara, ti oun si n san ọna lati lọ kọ ẹkọ nile iwe giga fasiti.

Oluwadamilare fikun pe, ni kete ti oun ba pari ẹkọ oun, ni oun yoo ni ki baba oun sinmi isẹ ẹmu dida.