Italy Parliament: Ìjọba gé aṣòfin àpapọ̀ láti 630 sí 400

ITALY Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Àwọn asòfin ilẹ̀ Italy ti dìbò láti gé iye àwọn asòfin lórílẹ̀èdè náà láti lè pèsè owó fún ìsèjọba orílẹ̀èdè náà.

Ile Asofin orilẹede Italy ti di ibo lati ge ida mẹta iye awọn asofin ti yoo ma a soju ẹkun kọọkan lorilẹede naa.

Ile asofin kekere buwọlu ofin to ni ki wọn ge iye awọn asofin lati Ojilelẹgbẹta o din mẹwa si irinwo, ti awọn asofin agba naa yoo si dinku lati okoolelọọdunrun o din marun si igba eniyan.

Igbesẹ yii wa lara ileri ibo ti ẹgbẹ oselu Five Star Movement, to je ijọba to wa ni ipo se fun awọn araalu lasiko ipolongo ibo rẹ.

Awọn asofin naa ni adinku to ba iye awọn asofin lorilẹede naa yoo jẹ ki orilẹede Italy ni ọgọọrọ miliọnu Euro nipamọ lati ara owo osu ati owona.

Amọ, awọn alariwisi ọrọ naa ni igbese yii yoo mu ifasẹyin ba isejọba tiwantiwa lorilẹede naa.

Bakan naa ni ofin tuntun naa ko le e wa si imusẹ a fi ti wọn ba se idibo gbogbo-gboo nitori yoo mu ayipada ba ofin orilẹede naa.

Related Topics