Bobrisky: Ogunye ní ìwà ìṣekúpani láìtọ́ wúwo ju ọ̀rọ̀ ‘kòsakọ́-kòṣabo’ lọ

Bobrisky Image copyright Instagram/bobrisky222

Ko sọrọ kankan ninu ohun tawọn kan sọ pe o yẹ ki awọn ko ṣakọ ko ṣabo ni ile igbọnsẹ tiwọn lawujọ, paapaa ni papakọ ofurufu ati awọn ibo miiran lawujọ.

Ilumọọka agbẹjọro, Jiti Ogunye to ba BBC sọrọ lo fidi ọrọ yii mu lẹ. Ogunye ni "melo ni eeyan bi Bobrisky lorilẹede Naijiria ti ijọba yoo fi kọ ile igbọnsẹ ọtọ fun wọn."

Agbẹjọro Ogunye ni, ọrọ runrun lọrọ naa nitori iṣoro to n koju orilẹede Naijiria pọ ju pe, ki ẹnikan maa sọ pe o yẹ kawọn ko ṣakọ, ko ṣabo ni ile igbọnsẹ ti wọn lọtọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amofin Ogunye ṣalaye pe, ofin ilẹ Naijiria gan an ko faye gba awọn ko ṣakọ ko ṣabo, nitorinaa, iru eleyi ko le fẹsẹ mu lẹ.

Ijọba apapọ lo kọkọ fi ikilọ lede nipa ewu to wa ninu kawọn eeyan bii Bobrisky maa ba awọn obinrin lo ibudo igbọnsẹ papọ.

Image copyright Facebook/Miss Sahahra

Ikede yii waye lẹyin ti rogbodiyan ṣẹlẹ ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe ni ilu Abuja, nigba ti wọn ri Bobrisky to n lo yara igbọnse awọn obinrin.

Ijọba wa rọ ẹka ilera lorilẹede Naijiria lati la awọn eniyan lọyẹ nipa ewu to wa ninu lilo yara igbọnse kan naa pẹlu Bobrisky, ti awọn eeyan kan si daba pe, ki wọn pese ile igbọnsẹ ọtọ fun awọn eeyan to jẹ ‘Kosakọ-Kosabo’ bii Bobrisky ati Miss Sahhara lawọn ibudo ajọlo.

Ṣugbọn amofin Ogunye ni awọn iṣẹlẹ bi awọn ọlọpaa ti wọn n ko awọn ara ilu satimọle lainidi, ọna ti ko dara, iṣekupa awọn ọmọ Naijiria lorilẹede India lo yẹ ki ijọba wa nnkan ṣe si bayii.

Image copyright Instagram Bobrisky222

Agbẹjọro Ogunye ṣalaye siwaju si pe, ofin Naijiria si n ri Bobrisky gẹgẹ bi ọkunrin ayafi to ba lọ ṣe ibura nile ẹjọ pe oun fẹ yipada lati ọkunrin si obinrin.

O fikun ọrọ rẹ pe awọn agbofinro lẹtọ lati fọwọ ofin mu un to ba lọ si ile igbọnsẹ awọn obinrin ni Naijiria.