Sex for Grades: Fásitì Eko ní kí olùkọ́ míì lọ fìdímọ́lé lori Fídíò BBC

Dr Samuel Oladipo Image copyright Facebook
Àkọlé àwòrán Ọjọgbọn Samuel Oladipo

Ile Ẹkọ fasiti ilu Eko ti jawe lọ joko sile folukọ miran ti o han ninu fiimu iwadii BBC eyi to ṣafihan awọn olukọ ni fasiti Ghana ati Naijria ti wọn dẹnu ifẹ ko awọn akẹkọbinrin.

Ọwọ tẹ ọjọgbọn Samuel Oladipo latari fiimu BBC ninu eyi to ti n kẹnu ifẹ si akọroyin BBC to ṣe bi akẹkọ.

Ohun ni olukọ kẹrin ti wọn yoo ni ki o lọ rọọku n'le latari ipa ti wọn ko ninu fiimu naa.

Lọjọ Aje ni Unilag kọkọ kede pe awọn ti ni ki ọjọgbọn Boniface Igbeneghu, tohun naa wa ninu fiimu ọhun lọ fidi mọle.

Ikede fasiti Eko yi waye lẹyin ti fasiti Ilu Ghana kede pe awọn naa ti ni ki awọn olukọ meji ti igba ṣi mọ lori ninu fọnran fidio naa lọ fidi mọle.

Mẹta ninu awọn olukọ yii Ọjọgbọn Oladipo, Ọmọwe Ransford Gyampo ati Ọjọgbọn Paul Kwame Butakor ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Iwaadi BBC naa ti awọn eeyan ti n kan sara si ṣafihan bi awọn olukọ ṣe n lo ipo wọn lati hu iwa aitọ pẹlu awọn akẹkọbinrin ni fasiti Eko ati Ghana.

Awọn fasiti mejeeji naa ni awọn lodi si ki awọn olukọ maa huwa aitọ pẹlu awọn akẹkọọ.