World tour- Jessica Nabongo ni obìnrin akọkọ nilẹ Africa tí yóò rin àgbaye tan

Eni ti o rin gbogbo agbaye tan Image copyright Jessica Nabongo
Àkọlé àwòrán World tour- Jessica Nabongo ni obìnrin akọkọ nilẹ Africa tí yóò rin àgbaye tan

Ninu ọdun yii ni Jessica Nabongo mu ero rẹ ṣẹ gẹgẹ bi obinrin akọkọ ni ilẹ Adulawọ ti yoo rin gbogbo orilẹ-ede agbaye.

Ni bayii, ọmọbinrin yii wa n fẹ ki ọpọlọpọ ojugba rẹ lati ilẹ Adulawọ naa gbiyanju lati mu ala ati ero wọn ṣẹ bii ti oun.

Ṣe ni ọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, ọdun yii ni Nabango, ọmọ ilẹ Uganda, ti a bi si ilẹ Amẹrika pari rinrin gbogbo orilẹ-ede agbaye ti o jẹ Aarundinnigba tan.

Bakan naa ni ẹni ti o jẹ Olugbani siṣẹ ajọ agbaye tẹlẹ ki arabinrin yii lori ẹro ayelujara fun iwa akọni rẹ lati rin iru irin ajo naa.

Ninu oṣu karun un ọdun yii ni o ṣi ṣalaye fun ile iṣẹ BBC wi pe irin ajo kaakakiri yii ti jẹ ki oun mọ bi o ṣe ri lati gbe igbe aye alaini.

O tẹsiwaju pe, oun gan paapaa ni ẹbi si Uganda ti ko si omi mimu fun wọn tabi ina mọnamọna.

O wa gba awọn obinrin nimọran lati ta giri si ala wọn lojuna ati maṣe bẹru ninu mimu ero wọn wa si imuṣẹ lai wo iru ẹya tabi aawọ ibi ti wọn ti wa.

Image copyright Jessica Nabongo
Àkọlé àwòrán Jessica Nabongo ọmọ ilẹ Uganda

Ko ṣai mẹnu baa wi pe, ki awọn obinrin o dẹkun wipe boya wọn ko le da rin irin ajo nitori ẹru tabi ifoya, o wi pe, irọ funfun balau ni iru ọrọ bẹẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTani otutu ma n mu ju laarin Ọkunrin ati Obinrin?

Nigba ti o n sọrọ nipa bi o ti ṣe ri owo, o ni oun ri iṣe to fi ri owo ni kete ti irin ajo ile iwe oun pari, oun si fi owo naa ra ile.

Gẹgẹ bi ko ṣe fẹran lati maa duro loju kan, o gba ile, o si tẹsiwaju lọ si ilẹ Japan lati lọ jẹ Olukọ ede Gẹẹsi.

Bakan naa ni o tun jẹ Olukọ ni ile iwe ẹkọ imọ nipa ọrọ okoowo ni ilu London, ki o to tun ṣiṣẹ pelu ajọ agbaye ti o gbe e de ilẹ Benin ati Italy.

Image copyright Jessica Nabongo
Àkọlé àwòrán Jessica Nabongo

Nibẹ ni o ti bẹrẹ si ni ko owo jọ, ti o si ṣe okoowo aṣọ ṣẹẹti wiwọ.

O ṣalaye pe lootọ ko dẹrun lati rin irin ajo bẹẹ gẹgẹ bi obinrin alawọ dudu, ti o tun gẹrun ori rẹ.

O ni iwa ẹlẹya mẹya ti ti oju oun ri ni ilẹ South Afrika ko kere ni pataki laarin awọn eniyan alawọ dudu ilẹ naa.

Bakan naa lo ni ọpọ ko fun oun ni wahala ni pataki ilẹ Senegal ti wọn fẹran eniyan dudu ti wọn si n kẹ gbogbo eniyan ibaa ṣe dudu tabi funfun.

O ni iwa awọn ọkunrin ilẹ Pakistan naa larinrin pupọ ti o si jẹ ọkan lara eyi ti o dara ju lọ.

Ko din ni Aadọjọ awọn eniyan ti o ti rin iru irin ajo bẹẹ sugbọn ti o jẹ pe Oyinbo alawọ funfun ni ọpọ wọn

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini Yoru[bá ń pe Necklace?