Ìjọba Ekiti n gbèrò òfin tí yóò fí ìjìyà titẹ lọ́dàá jẹ àwọn afipábánilòpọ̀

Aworan awọn oluwode to n pe fun ijiyia to tọ fawọn afipabilopọ Image copyright Getty Images

Ti aba afikun ijiya titẹ awọn to ba fipabanilopo ba di gbigba wọle, nnkan ko ni ṣẹnu 're fawọn to n hu iwa aburu yii ni ipinlẹ Ekiti.

Afikun ijiya yii ti iyawo Gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayemi n ṣagbatẹru rẹ lawọn onwoye ni o ti wa di dandan bayii bi ọwọja ifipabanilopọ̀ paapa pẹlu awọn ọmọde ti ṣe gbode.

Lasiko ti wọn n ṣe agbeyẹwo ofin yii ni ile aṣofin ipinlẹ Ekiti ni iyawo Gomina ati agbẹjọro agba to tun jẹ kọmisana feto idajọ Wale Fapohunda tẹnumọ pataki afikun ofin naa.

Image copyright Facebook/bisiafayemi

Fapohunda rọ awọn aṣofin ipinlẹ naa lati jara mọ ijiroro lori ofin yii lati le ran ilakaka Gomina Fayemi nipa kikoju ifipabanilopọ ati awọn iwa aburu mi lawujọ.

Ṣaaju ni ipinlẹ Ekiti ti ni ofin kan to n koju iwa ipa laarin akọ tabi abo ṣugbọn afikun ofin yIi yoo tubọ gba'gbara fawọn alaṣẹ lati koju awọn alaburu.

Aya Gomina ni niṣe ni awọn eeyan ma n fojojumọ gbe ọrọ ifiipabanilopo wa si ọfIisi oun ti o si ti wa di dandan bayIi lati jẹ ki awọn to fara kasa iṣẹlẹ yiI ni ọna abayọ.

Lara awọn ohun ti ofin naa tun fẹ koju ti atunṣe ọ̀hun ba waye ni pe wọn yoo da awọn aaye ifẹjọsun silẹ kaakiri ti awọn eeyan ko si ni maa wa si olu ilu Ekiti ki wọn to fẹjọ iwa ifipabanilopo ati awọn ẹṣẹ mii sun mọ.