Lagos Police: Tí ìrònú bá ti pọjù , ó le ṣokùnfa àìṣiṣí nǹkan ọmọkùnrin

Ọlọpaa tí wọn daabobo ara ilu Image copyright Nigeria Police
Àkọlé àwòrán Ọlọpapa Ilẹ Naijiria

Obinrin kan ti ko si ẹni ti o mọ orukọ rẹ titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ ni wọn fi ẹsun rírá nkan ọmọkunrin kan ninu ọkọ ninu Eko.

Iroyin ti o tẹ ikọ BBC lọwọ ni wi pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ni ibudokọ Onipanu ni llu Eko.

Nigba ti Alukoro ajọ Ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Bala Elkana, n ṣalaye fun ile iṣẹ BBC lori ọrọ naa, o ni Ọlọpaa ko gbagbọ ninu iru iṣẹlẹ bẹẹ.

O tẹsiwaju pe, nigba ti awuyewuye ọrọ yii ṣẹlẹ ni wọn fi to ọlọpaa leti ti wọn si gbe igbesẹ lati doola ẹmi arabinrin ọhun ẹni ti iwadii si n lọ lọwọ lori ọrọ rẹ.

Bala ṣalaye pe ofin ko gbagbọ ninu ọrọ naa tori pe ọpọ igba ni iru nkan bẹẹ n ṣẹlẹ ti o jẹ pe ti ironu ba ti pọ ju yoo ṣokunfa irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ.

Alukoro naa wa ṣalaye pe, awọn ẹni ti ọrọ naa kan ni wọn ti ko lọ si ile iwosan fun itọju ti wọn si ti n fun ni itọju ti o peye bakan naa.

Ajọ ọlọpaa ti mu obinrin naa sọdọ fun aabo ati idoola ẹmi rẹ lọwọ awọn ti inu n bi ki wọn ma baa ṣe ẹmi rẹ legbodo.

Image copyright BRT
Àkọlé àwòrán Inu ọkọ Akero ni Ilu Eko

Ile iṣẹ Ọlọpaa ni Onipanu ni ilu Eko ni obinrin naa wa ti gbogbo ẹjọ naa si ti n lọ ṣugbọn idaniloju wa pe, ohun gbogbo yoo pada bọ sipo laipẹ.

Ọlọpaa ni ko si ami idaniloju pe obinrin ti wọn fi ẹsun kan yii ṣe iru nkan bẹẹ ṣugbọn ti wọn kọ gbiyanju lati diimu nitori pe o joko si ẹgbẹ wọn.