Busa 2019: Sadiya Umar Farouq - Obìnrin Olóṣelú tó lààmì laaka.

Sadiya Image copyright @sadiya
Àkọlé àwòrán Ko si ẹni ti ko le ṣe igbeyawo nigba to ba wuu

Lati bii ọjọ mẹta ni iroyin ti gba ori ayelujara pe Aarẹ Muhammadu Buhari fẹ fẹ iyawo keji.

Iroyin naa ni Sadiya Umar Farouq ni ade naa fẹ ṣi mọ lori ṣugbọn ko tii si aridaju iṣẹlẹ yii lati ileeṣẹ aarẹ titi di asiko yii.

Ta ni Sadiya ti ariwo pọ lori rẹ yii?

Sadiya Farouq ti fi igba kan jẹ Akapo ẹgbẹ oṣelu APC laarin oṣu kefa, ọdun 2013 si oṣu kẹfa, ọdun 2014.

O tun ṣe Akapo ẹgbẹ oṣelu CPC ti o jẹ ọkan lara ẹgbẹ ti o parapọ ni ọdun 2013 di APC, ti o jẹ ẹgbẹ alatako ti o tobi julọ to si gba ijọba lọwọ ẹgbẹ PDPWo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn obìnrin méje ti Buhari fẹ́ yàn sípò minista .

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Iroyin to gba ayelujara kan ni pe, o maa to o ko wa ile Aarẹ Buhari

Ijọba lbilẹ Zurmi ni Ipinlẹ Zamfara ni a gbe bii.

O lọ si ile iwe Ijọba apapọ ti o jẹ kiki obinrin ni ilu Gusau, ni Ipinlẹ Zamfara naa.

Image copyright OTHER
Àkọlé àwòrán Sadiya Umar Farouq - Obìnrin Olóṣelú tó lààmì laaka.

Ile Iwe Fasiti ti Ahmadu Bello ni Zaria, ni Ipinlẹ Kaduna ni o ti kẹkọọ gboye ninu Eto Idokowo ni ọdun 1998 ti o tun gunlẹ onipele keji [Masters Degree] lori eto ilẹ okeere.

O gba oye ipele keji yii ni ọdun 2008 ati ipele keji miran lori Idokowo [MBA] ni ọdun 2011 ni ile iwe Fasiti Ahmadu Bello ,Zaria, ni Ipinlẹ Kaduna.

Image copyright Sadiya
Àkọlé àwòrán Sadiya Umar Farouq

O ti ṣiṣẹ ni ọpọlọpọ ile iṣẹ bii Ọga Agba fun igbokegbodo ni Pinnacle Travels and Tours, laarin ọdun 2001 si ọdun 2003 ki o to darapọ mọ ajọ ti o n risi eto ọrọ ile Igbimọ.

Sadiya ni wọn yan gẹgẹ bi Kọmiṣọmma Ijọba apapọ lori ọrọ awọn atipo ati awọn ti ko rile gbe ni Oṣu kẹsan an, ọdun 2016.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini Yoru[bá ń pe Necklace?

Ori Ipo yii lo wa di Oṣu kẹjọ, Ọdun 2019 ki o to di Minisita fun Abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede yii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCS Mum: Omotolani Ekene ní ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ọ̀lẹ, arugún, aláìlera ni ẹni tó fi abẹ bímọ