BUSA19: Bí ètò ìgbéyàwó ààrẹ Buhari kò bá ṣe lọ rèé -àwọn ènìyàn Nàíjíríà

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Lẹyin to ti hande pe iroyin ẹlẹjẹ ni igbeyawo aarẹ Buhari ti awọn eeyan n pariwo lori ayelujara; sibẹ ọpọ aworan to panilẹrin fun ipalẹmọ lo kun ayelujara bayii

Oriṣiiriṣi aworan ati akọle to pani lẹrin lo ti kun ori ayelujara ni eyi ti awọn eniyan fi n ṣeto ipalẹmọ igbeyawo ofege ti wọn ni o yẹ ko waye laarin Aarẹ Buhari ati Hajiya Sadiya Umar Farouq.

Ṣaaju ni iroyin ẹlẹjẹ ti gba ori ayelujara pe eto igbeyawo naa yoo waye laarin minista tuntun fun Abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede ati aarẹ Naijiria.

Ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn n gbiyanju lati mọ Ta ni Sadiya Umar Farouq tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ń gbé pé òun ló fẹ́ dí ìyàwó tuntun Buhari? jẹ́.

Ṣugbọn lẹyin pe gbogbo nkan to n jade lati ọdọ awọn ti ọrọ kan fihan pe irọ to jina si ootọ ni iroyin ẹlẹjẹ naa; sibẹsibẹ ayelujara ti kun fun oriṣiriṣi aworan ati akọle to fihan pe apanilẹrin ni awọn eniyan Naijiria.

Wo diẹ lara akọle ati awọn aworan apanilẹrin to wa lori ayelujara:

Lóòni ni ayẹyẹ ìgbéyàwó ààrẹ Buhari ni'lù Abuja ni eyi ti ero ti n de si Abuja:

Image copyright Ogundamisi
Àkọlé àwòrán Awọ asọ oni ni Pepper-Dem Green àti Wailers white

Ní bayìí àwọn èèkan ilú, àwọn olóṣèlú àwọn ọmọ Naijiria jákejádo lo ti si nń gúnlẹ̀ sí ìlú Abuja.

Image copyright Kayodebarkre
Àkọlé àwòrán Ebora owu naa ti de ibi ayẹyẹ

Nínú ètò ti yóò wáye ni mọsàlási Jimoh nílùú Abuja lásìkò irún Jimoh toni ní wọn ti maa so wọn pọ.

Image copyright MrLekan Adigun
Àkọlé àwòrán Awon eekan ninu PDP naa de bẹ

Láìpẹ́ yìí ìròyìn kan déedé bẹ̀rẹ̀ si ni ja rainrain lójú opó twitter pe ààrẹ orilẹ̀-èdè Nàijíríà Muhammadu Buhari yóò fẹ́ ìyàwó tuntun sáàfin.

Image copyright Ayourb
Àkọlé àwòrán Awọn aarẹ orile-ede naa ti de silu Abuja

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn yìí ko fẹ́sẹ̀ múlẹ, ti ko si si oun a ri gbámu kankan níbẹ̀, ọ̀pọ ọmọ Naijiria ti pari bi gbogbo ǹkan yóò ṣe lọ leto leto.

Image copyright @ogbeni_Skrtel twitter
Àkọlé àwòrán Arakunrin Ondo àti awọn gomina ilẹ Yoruba

Oko iyawo ti n mura bayii:

Láti ori ìwé ìpè àlejo tó si mo adari ètò ounjé, àti adari ounjẹ ní wọ́n ti fóju wọ́n han bàyìí:

Image copyright QOlakul
Àkọlé àwòrán Oko iyawo ti wọ agbo
Image copyright Imaam Shams
Àkọlé àwòrán Eto iyawo ti bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹwu

Nínú ètò ti yóò wáye ni mọsàlási Jimoh nílùú Abuja lásìkò irún Jimoh toni ní wọn ti maa so wọn pọ.

Image copyright Osi_Suave
Àkọlé àwòrán Awon olorin ati osere tiata

Awọn alejo miran ti awọn eniyan n ṣe awada pe o ti de sibi eto naa ni:

Image copyright Iwara139
Àkọlé àwòrán Bobbriski lo wọ pepper-dem green yii oo
Image copyright Optimistic-Ade
Àkọlé àwòrán Abubakar Atiku bawọn n dáwọ idunnu nibẹ
Image copyright Hassan winger
Àkọlé àwòrán Dino ati àwọn ẹmẹwaa rẹ sááju ọjọ igbeyawo lọ ki Baba Buhari

Ayẹyẹ yiìí ko yọ Trump silẹ bi o se fí ohun ránsẹ pé òun ko ni le raye wá.

Image copyright Ayo Akanji
Àkọlé àwòrán Em aa binu si mi pe mi o ni le yóju, ọ̀rọ̀ Turkey ati Kurdish lo fàá

Àwọn tí ìbàdan, ní ìpínlẹ̀ Oyo, Porthacourt àti Imo

Image copyright Tajudeen Olajide
Àkọlé àwòrán Micra lawọn ara Ibadan yoo gbe de Abuja lati yẹ ọkọ iyawo sí
Image copyright H cookey
Àkọlé àwòrán Awon tori omi o gbẹ́yìn

Ọkọ ìyàwọ ti de nínú ọkọ bọginin rẹ̀ ti àwọn alábarin àti olólùfẹ́ rẹ̀ si n wọ́ tẹ̀le.

Image copyright Kola Stephen
Àkọlé àwòrán Awon ti pota ree ni Garaji ọkọ

Wọn ni asọ ti yóò lé wọ òde ìgbéyawo náà ni Pepper-dem àtio wailers White

Ìyá Micho àti awọn alágbàse míràn lo soju nibi iyẹyẹ náà

Image copyright AbiolaGenus8
Àkọlé àwòrán Awọn olunjẹ ti bẹ̀rẹ̀ si ni in ounjẹ
Image copyright Johannx
Àkọlé àwòrán Mr JAG naa wa lara awon kongila olounje
Image copyright Bolatito
Àkọlé àwòrán Awon ounjẹ to joju ni gbese
Image copyright Bolabelyncon
Àkọlé àwòrán Mo gbo moya ti fẹ pari oujẹ inawo

Alaga idúro fú ìdíle ayẹyẹ igbeyawo náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni pẹrẹwu

Image copyright Modabba
Àkọlé àwòrán Ogbeni Raufu ti bẹ̀rẹ̀ isẹ́
Image copyright Bababosso
Àkọlé àwòrán Won ti bẹ̀rẹ̀ sinu gbọ́wọ́ ijo gẹngẹ

Gbogbo elere fún ayẹyẹ naa ooo

Image copyright Lucasscot_101
Àkọlé àwòrán Igbakeji àarẹ ni Gbogbo elere nibi ode yii
Image copyright Optimistic_Ade
Àkọlé àwòrán Ààrẹ aná ni Naijiria, tí n mura silẹ fun ayẹyẹ yìí
Image copyright HelloMilez
Àkọlé àwòrán Awon Orẹ Oko

Awọn asọna fun ayẹyẹ igbeyawo naa

Image copyright @Uwayasi
Àkọlé àwòrán Awon asona ti yóò ma ran alejo lọ́wọ́ nibi ayẹyẹ yii

Minisita fun ere idaraya tẹlẹ ni odẹ aperin ti yóò pese gbogbẹlan ti wan nilo.

Image copyright Lugard Fredo
Àkọlé àwòrán Minisita fun ere idaraya tẹlẹ ni odẹ aperin ti yóò pese gbogbẹlan ti wan nilo

Awọn ọmọ Naijiria ba fi fidio bi igbeyawo naa ṣe lọ sita pe:

Image copyright BadMAnLade
Àkọlé àwòrán Awon mogbọ moya rèé ti wan mu iwe iwole dani

E seun ti ẹ wa, ẹbun àmurele rèé fun gbogbo awọn ti wan wa fun ayẹyẹ igbéyawo yìí:

Image copyright #sirtunji
Àkọlé àwòrán Awọn ẹbun ti wọ́n pin fun alejo

Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?

Èmi kò fẹ́ Aàrẹ Buhari o- Sadiya Umar Farouq

Lati bii ọjọ mẹta kan ni iroyin ti gba ori ayelujara kan pe Aarẹ Muhammadu Buhari to n tukọ Naijiria fẹ gbe iyawo miran le Ayisha aya rẹ.

Opọ awọn eniyan ni wọn n woye pe Ta ni Sadiya Umar Farouq tí ìròyìn ń gbé pé òun ló fẹ́ dí ìyàwó tuntun Buhari?

Nigba ti Ileeṣẹ BBC kan si awọn ti ọrọ kan naa ni wọn fidiẹ mulẹ pe iroyin ẹlẹjẹ ni o.

Image copyright @Sadiya
Àkọlé àwòrán Ẹ yee parọ mọ mi o! Emi ko fẹ aarẹ Buhari -Sadiya Umar Farouq

Eni ti a ba sọrọ ni ọdọ Hajiya Sadiya Umar Farouq to jẹ minista tuntun tijọba Buhari yan fun ileeṣẹ ijọba apapọ tuntun ni Abuja ni Hajiya Sadiya wa ni Geneva bayii ni eyi to fihan pe irọ pata to jina si otitọ ni ọrọ naa.

Oṣu kẹjọ, Ọdun 2019 lo di Minisita fun Abojuto lori ọrọ Ijamba ati Igbayegbadun ọmọniyan lorilẹ-ede yii Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn obìnrin méje ti Buhari fẹ́ yàn sípò minista.

Kini ootọ inu Fidio ti Ayisha ti n binu to n tan lori ayelujara bayii?

Nigba ti BBC bere nipa fidio to ṣafihan Ayisha to n binu lori ayelujara, pe:

" ........ Kini o de ti o fi n ti lẹkun?....... A ni o le nigba awọn ọmọ ogun ni Aso Rock yatọ si igba ọlọpaa to n ṣọ wa.....O to gẹ........ awọn oponu dede...."

Bakan naa ni ẹni ti BBC ba sọrọ nile iṣẹ aarẹ to ni ki a ma darukọ oun ṣalaye pe irọ to jina si ootọ ni pe wọn dé aya aarẹ Buhari, Aisha mọ́lé ninu Aso Rock.

Ọkan lara awọn oluranlọwọ Aisha Buhari ti BBC ba sọrọ naa ṣalaye pe fidio naa ti pẹ.

O ni fidio naa kii ṣe ohun to n ṣẹlẹ bayii rara.

Ati pe irọ ni ohun ti wọn n sọ lori ayelujara pe Aisha de pẹlu ibinu si Aso Rock ni ana.

Nipari o ni Ayisha Buhari ti lọ si London lati bii oṣu mẹrin sẹyin ni eyi ti o ni nitootọ ni irinajo yii ti n fa wahala diẹdiẹ laarin aarẹ Buhari ati Aisha aya rẹ.

Sadiya Umar Farouq ti wọn pori ẹ ninu ọrọ yii paapaa ni oun ko si ni Naijiria lasiko yii nitori o ti ba ọrọ bi yoo ṣe dara lọ si Geneva lati bii ọjọ melo sẹyin.