Dino Melaye: Bí mo tilẹ̀ fìdí rẹmi, mo f'ọpẹ́ fún Ọlọ́run

Aṣofin orilẹede Naijiria, Sẹnetọ Dino Melaye ti fidi rẹmi nile ẹjọ lori ibo to gbe e wọle gẹgẹ bii sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Iwọ Oorun ipinlẹ Kogi.
Dino Melaye funrarẹ fi iroyin yii sita loju opo Twitter rẹ pe, oun fidi rẹmi o ṣugbọn ninu ohun gbogbo, ọpẹ ni fun ọlọrun to bẹrẹ ohun gbogbo ti yoo si yọri rẹ.
- Kí wọ́n tún ìbò Kogi dì nígbà 2,000 Dino ló máa wọle- Dino
- Ọlọ́pàá f'aṣọ bójú gbé Dino kúrò nílé ìwòsàn

Melaye ni oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo oṣu keji ọdun 2019.
Ẹwẹ, ṣe ni oludije Smart Adeyemi to wa ni ẹgbẹ alatako, All Progressives Congress (APC) fun ipo kan naa pe jijawe olubori rẹ nija nile ẹjọ.
Awọn ẹsun ti Smart fi kan Dino da lori ohun mẹta iyẹn ṣegeṣege eto idibo, nini ibo to koja iye to yẹ ati aitẹle ofin eto idibo.
- Ìbéèrè àti ìdáhùn pẹ̀lú Seyi Awolowo ti BBNaija lórí BBC Yorùbá
- Ẹṣẹ wo ni Ambode ṣẹ̀ tí ilé aṣòfin Eko fẹ́ fí ọlọ́pàá mú u?
- Ta ni Sadiya Umar Farouq tí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ń gbé pé òun ló fẹ́ dí ìyàwó tuntun Buhari?
- Láìníifiṣe pé wọ́n ti ni ìròyìn òfegè ni pé Aarẹ Buhari fẹ gbé Sadiya níyàwó, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára
Nitorinaa awọn adajọ gba ipẹjọ Smart wọn si pe fun atundi ibo. Ninu eyi ni Sẹnetọ Dino Melaye ti kede pe oun fidi rẹmi bayii.
Ṣugbọn o kasẹ ọrọ nilẹ pe Ọlọrun to bẹrẹ ohun gbogbo na ni yoo ṣe aṣepe rẹ.